Dapọ Abiọdun fun akẹkọọ Ogun to yege ju lọ ni LASU ni miliọnu meji naira ati ile kan

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Idunnu ṣubu lu ayọ fawọn akẹkọọ meji kan, Ọladimeji Ṣotunde, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun to pegede ju lọ ni Yunifasiti LASU, l’Ekoo, ati ọmọbinrin kan, Faith Ọdunsi, akẹkọọ ileewe Girama  Ambassadors College, Ọta, to ṣe daadaa ju lọ ninu imọ iṣiro lagbaaye,nigba ti Gomina fun Ọladimeji ni miliọnu meji ati ile kan, to si fi milliọnu marun-un naira si asunwọn iranlọwọ ti wọn ṣi fun Faith Ọdunsi.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin yii, ni eto naa waye l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta. Bi Ọladimeji ṣe pegede ni LASU, bẹẹ ni Faith toun jẹ akẹkọọ nileewe girama naa jawe olubori ninu idije ẹkọ nipa iṣiro ti wọn pe ni ‘ Global Open Mathematics Tournament.’

Nibi eto ti wọn tun fi da awọn olukọ to yẹ lọla naa ni Gomina Dapọ Abiọdun ti sọ pe awọn eeyan to gba ami-ẹyẹ yii tubọ gbe ipinlẹ Ogun sori atẹ agbaye ni, o ni wọn ti gbe ipinlẹ yii ga, idi si niyẹn tijọba fi mọ riri wọn.

Abiọdun sọ pe ijọba oun yoo maa ṣe ẹtọ to yẹ bayii fawọn akẹkọọ ati olukọ nipinlẹ Ogun, lati maa jẹ koriya fun wọn, ti yoo si maa jẹ nnkan idagbasoke ati iyi nla fun ipinlẹ yii kaakiri agbaye.

Awọn ọmọwe nla bii Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, Ọjọgbọn Adewale Ṣolarin, Ọjọgbọn Isiaq Oloyede atawọn mi-in ni wọn ki Gomina Abiọdun fun bo ṣe mu ẹkọ ni koko, wọn ni ohun to fa aṣeyọri awọn akẹkọọ yii atawọn olukọ wọn niyẹn.

Leave a Reply