Dapọ Abiọdun fun ẹgbẹ awọn ologun to ṣubu loju ija lowo, ọkada meji ati ọkọ ayọkẹlẹ kan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati ran mọlẹbi awọn ologun to ti ku atawọn to fara pa pẹlu awọn to ti fẹyinyiti lọwọ nipinlẹ Ogun, miliọnu mẹwaa naira, ọkada meji ati mọto ayọkẹlẹ kan ni Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun, fi ta ẹgbẹ ‘The Nigerian Legion’ to n ri sọrọ awọn ologun naa lọrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.

Ọfiisi Gomina to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, leyi ti waye, nigba ti wọn n ṣe ifilọlẹ ọsẹ iranti awọn ologun ti wọn ba ogun lọ nitori ifẹ ilu.

Lasiko ti gomina n fi awọn ẹbun naa tọrẹ fẹgbẹ yii lo rọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria, awọn ileeṣẹ atawọn alẹnulọrọ lawujọ lati ṣe iranlọwọ owo atawọn nnkan mi-in fawọn opo tawọn ologun wọnyi fi silẹ, awọn obi wọn atawọn ọmọ.

Gomina Abiọdun ṣalaye pe bawọn eeyan ba n ṣeranwọ yii fawọn to tọ si, yoo jẹ ki ifẹ ati irẹpọ wa laarin araalu atawọn ologun to n fi ẹmi wọn wewu lọ soju ogun nitori alaafia araalu. O fi kun un pe nipinlẹ Ogun yii, ijọba ko ni i yee mọ riri awọn ologun  fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati ran ipinlẹ yii lọwọ, bẹẹ lo dupẹ lọwọ wọn fun iṣẹ aabo ti wọn ṣe lasiko iwọde SARS.

Nigba to n dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun, Alaga Legion nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Oloyede Taofeek, sọ pe ọpọlọpọ nnkan tawọn ko le ṣe tẹlẹ ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin lo ti ṣee ṣe bayii, nitori anawọsi ijọba to pọ si ni.

Leave a Reply