Dapọ Abiọdun gbe igbimọ ti yoo ri si ifiyajẹni awọn ọlọpaa dide l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abeokuta

Pẹlu bi ifẹhonuhan awọn ọdọ ṣe n lọ lọwọ, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo maa ri si awọn ẹsun ifiyajẹni tawọn eeyan n fẹsun ẹ kan awọn ọlọpaa, Adajọ-fẹyinti Solomon Olugbemi ni gomina yan gẹgẹ bii alaga igbimọ naa.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa yii, lo ti ni igbesẹ yii waye ni ibamu pẹlu ipade ti Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ṣe pẹlu awọn gomina ipinlẹ kaakiri lori iwọde to n lọ lọwọ.

Ninu ipade naa ni wọn ti fẹnuko pe kawọn gomina ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo maa gbọ ẹjọ awọn tawọn ọlọpaa ba fiya jẹ. Ki wọn si ṣeto ‘gba-ma-binu’ fawọn ti ijamba ba kan.

Diẹ ninu awọn to wa ninu igbimọ naa yatọ si alaga wọn ni: Kọmureedi Ọlayinka Fọlarin, Arabinrin Omonajevwe Janet Abiri, Kọmureedi Abduljabar Ayelaagbe, Kọmureedi Bamgboṣe Tọmiwa atawọn mi-in.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, ọsẹ to n bọ yii ni igbimọ naa yoo di bẹrẹ iṣẹ.

Leave a Reply