Dapọ Abiọdun kilọ fawọn to n da rogbodiyan silẹ ni Yewa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

 

Latari rogbodiyan to mu ẹmi lọ to n waye lawọn àgbegbe Yewa, nipinlẹ Ogun, lasiko yii, Gomina Dapọ Abiọdun ti kilọ fawọn to wa nidii iṣẹlẹ naa. O ni ijọba oun ko ni i faaye gba palapala bẹẹ. Ẹni tọwọ ba si ba nidii ẹ yoo jẹ buruku iya.

Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji yii, ni gomina kilọ bẹẹ, ninu atẹjade kan lati ọfiisi Akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin.

Ṣe lọjọ naa ni iroyin jade pe awọn Fulani paayan ni Owode-Ketu, pe wọn tun daamu awọn eeyan Igan -Alade, Eegua ati Igbogila.

Yatọ si ikilọ yii, ikọ alaabo ti i ṣe ọlọpaa, fijilante, otelemuye atawọn ẹṣọ mi-in nijọba làwọn ti da sawọn agbegbe ti rogbodiyan ti n ṣẹlẹ, awọn agbegbe bíi Ariwa Yewa, Ìmẹ̀kọ-Afọn ati Guusu Yewa.

Wahala naa pọ lawọn agbegbe yii to bẹẹ ti wọn ti ileewe ati ọpọlọpọ ibi pa. Eyi lo fa a ti Gomina fi ni ki iwadii bẹ̀rẹ̀ kia lori awọn to lọwọ si ikọlu to mu ẹmi lọ naa, wọn ni ijọba yoo gbe ẹni tọwọ ba tẹ pe o lọ́wọ́ si wahala naa lọ si kootu kíá ni.

“Gbogbo ohun to ba gba la maa fun un lati mu alaafia duro nipinlẹ Ogun, koda bo gba ifiyajẹni gidi, a o ni i woju ẹnikẹni ka too lo o lati mu ifọkanbalẹ wa nipinlẹ yii”

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Leave a Reply