Dapọ Abiọdun ko ọpọlọpọ mọto fawọn ọlọpaa nitori iṣẹ aabo

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko din ni mọto ayọkẹlẹ marundinlogoji (35), ọkọ akero-kẹru ogun (20), ẹwu akọtami igba (200), pẹlu akoto tawọn ọlọpaa yoo maa de sori ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun, ko fun ọga agba ọlọpaa tuntun lorilẹ-ede yii, IGP Alkali Baba Usman, lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa, niluu Abẹokuta, nitori ki idẹrun tun le de ba awọn ọlọpaa nipa ipese aabo faraalu.

Nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ naa ni ọga ọlọpaa tuntun tijọba apapọ ṣẹṣẹ fọwọ si iyansipo rẹ naa de si gbagede igbalejo to wa l’Okemosan, l’Abẹokuta, nibi ti Gomina Abiọdun ati Igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Oyedele Salakọ, ti gba a lalejo.

Nigba to n fa awọn nnkan irinṣẹ yii le Alkali lọwọ, ti ọkunrin naa si pada ba wọn ṣi i, Abiọdun ṣalaye pe awọn nnkan eelo tọlọpaa yoo fi maa ṣiṣẹ wọn bayii ṣe pataki pupọ, paapaa lasiko yii ti eto aabo mẹhẹ.

O ni eyi lo fa a tijọba oun tun fi ṣafikun awọn ọkọ toun ti pin fawọn agbofinro tẹlẹ.

Gomina rọ wọn lati ri i pe wọn lo awọn ọkọ ati nnkan eelo to ku fun iṣẹ aabo tijọba tori ẹ ko wọn kalẹ, ki wọn si maa ri i daju pe wọn n fọwọsowọpọ pẹlu araalu.

  Lẹyin ti ọga ọlọpaa pata naa ba wọn ṣi awọn nnkan eelo yii tan lo kọja si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, nibẹ ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun, ti ṣalaye fun ọga rẹ agba naa pe iṣoro meji lo n koju ipinlẹ Ogun.

O ni awọn to n fojoojumọ pariwo idasilẹ Orilẹ-ede Oduduwa, ti wọn n ṣewọde kiri, n fa wahala, bawọn ọlọpaa si ṣe n da wọn lẹkun to ni wọn tun tẹpẹlẹ mọ iwọde onijagidijagan naa, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa paapaa ti ṣetan fun wọn.

Iṣoro awọn onifayawọ ni Ajogun ka ṣikeji. O lawọn eeyan naa maa n pa awọn kọsitọọmu atawọn to n ri si iwọle-ijade arinrin-ajo (Imigireṣan), lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ oojo wọn.

Ajogun ko ṣai sọrọ nipa awọn to lọọ ṣi ẹnuboode (Bọda silẹ) laipẹ yii, o ni awọn onijagidijagan to n daamu ọlọpaa naa niyẹn.

Nigba to n sọrọ, ọga  ọlọpaa patapata ni Naijiria, Alkali Baba Usman, ṣalaye pe ijọba to n ṣatilẹyin fọlọpaa ni wọn ni nipinlẹ Ogun yii. O ni iyẹn lo jẹ ki gomina gbe ọrọ wọn sọkan to si n ra nnkan eelo fun wọn.

Ọga ọlọpaa pata gba awọn ọmọọṣẹ rẹ nimọran lati ma ṣe ja gomina yii kulẹ, o ni ki wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn si ma joye ẹni to kan n sare tẹle ọdaran kiri.

Baba Usman tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa ipinlẹ yii ko gbọdọ foju pa araalu rẹ. O ni araalu mọ ole, wọn mọ oniṣẹ ibi laarin wọn. Bi ọlọpaa ba fọwọsowọpọ pẹlu araalu, ti wọn jọ ṣiṣẹ pọ, Alkali sọ pe wẹrẹ niṣẹ ọlọpaa yoo maa yọri si rere, awọn eeyan yoo si maa mọ riri iṣẹ wọn.

Baba Usman ko ṣai gba awọn ẹgbẹ akẹkọọ to waa yẹ ẹ si nimọran nla. O ni gbogbo nnkan kọ ni ijangbara tabi jija fun ara yooku.

Baba sọ pe keeyan kawe ẹ to fẹẹ ka ko jade kia niyi akẹkọọ, ki i ṣe keeyan maa fi ọdun meje kawe ọdun mẹrin, ko si maa pariwo ‘Aluta n tẹsiwaju’ kaakiri. Nitori ọjọ iwaju lo ṣe pataki, to si maa tọjọ ju Aluta fifa kiri lọ.

Leave a Reply