Dapọ Abiọdun naa sanwo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

  Idunnu ti ṣubu lu ayọ fawọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ogun bayii, pẹlu bi ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ṣe dẹrin-in pa ẹẹkẹ wọn nipari oṣu kẹwaa, ti wọn sanwo oṣu tuntun fun wọn pẹlu afikun.

Ṣe ẹgbẹrun lọna ọgbọn lowo-oṣu to kere ju tawọn oṣiṣẹ n beere fun tipẹ, ṣugbọn Gomina Abiọdun fi ẹẹdẹgbẹta naira (500) kun tiẹ, iyẹn lo fi jẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn ati ẹẹdẹgbẹta naira ni oṣiṣẹ to ba gbowo to kere ju nipinlẹ yii yoo maa gba loṣooṣu (30,500).

Lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ALAROYE ba olori Ajọ oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress, nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Emmanuel Bankọle sọrọ. Ọkunrin naa fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni, ijọba Dapọ Abiọdun ti mu ileri ẹ ṣẹ, awọn oṣiṣẹ ti n gba owo-oṣu tuntun naa lati ipari oṣu kẹwaa, bi wọn yoo si ṣe maa gba a lọ niyẹn.

O dupẹ lọwọ gomina lorukọ awọn oṣiṣẹ, o si rọ ijọba lati tun foju wo awọn nnkan mi-in tawọn oṣiṣẹ n beere lọwọ wọn.

Bakan naa ni Alaga awọn tiṣa nileewe girama nipinlẹ Ogun, iyẹn Academic Staff  Union of Secondary School (ASUS), Kọmureedi Akeem Lasisi, fidi ẹ mulẹ fun wa pe loootọ lawọn tiṣa ti ri alaati ipari oṣu kẹwaa, iṣiro owo oṣu tuntun nijọba si san fun wọn.

Lasisi to tun jẹ Adele alaga TUC nipinlẹ yii dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun. O ni awọn mọ riri afikun owo to ṣe naa, ṣugbọn agbatan la a gba ọlẹ ni kijọba fi oore yii ṣe, gbogbo ibi to ku tawọn n bẹbẹ fun, ki wọn ba awọn bu ororo itura si i.

 

 

Leave a Reply