Dapọ Abiọdun ni ki wọn wadii ija Fulani atawọn agbẹ nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti i ṣe gomina ipinlẹ Ogun ti paṣẹ fawọn agbofinro nipinlẹ yii lati wadii rogbodiyan to ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn Fulani lagbegbe Yewa lọsẹ to kọja, nibi ti ẹmi ẹni kan ti ṣofo, ti wọn si ba awọn dukia jẹ.

Atẹjade to ti ọfiisi Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomorin, wa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu keji yii, lo sọ eyi di mimọ.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti fi ye awọn akọroyin pe yatọ si pe awọn ọlọpaa yoo wadii iṣẹlẹ yii, ijọba ti gbe ikọ ti yoo maa gbogun ti ikọlu iru eyi to waye ni Egua, lọsẹ to kọja yii dide.

 Wọn ni ikọ naa ni yoo jẹ ti awọn ẹṣọ alaabo oriṣiiriṣii ti wọn yoo maa rin kiri awọn agbegbe lati pako dina iru ikọlu yii. Bi ikọlu ba si waye, wọn yoo wa nitosi lati tete ri ọwọ rẹ bọlẹ.

‘‘A ko ni i gba iwa ọdaran kankan laaye nipinlẹ yii, a ko fẹẹ mọ iru ẹni yoowu ko jẹ. Ijọba ti pa awọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku laṣẹ lati mu awọn to lọwọ si eyi to ṣẹlẹ kọja yii, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn. A ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati ba alaafia ipinlẹ Ogun jẹ, ẹnikẹni to ba si fẹẹ da omi alaafia ilu ru yoo da ara rẹ lebi.’’ Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Nigba to n ba ẹbi to padanu eeyan wọn kẹdun, Gomina Abiọdun ba awọn ti wọn padanu ilẹ oko wọn naa kẹdun pẹlu, atawọn to jẹ pe maaluu wọn lo ba wahala naa lọ.

 O rọ awọn araalu lati maa ba iṣẹ oojo wọn lọ lai si ikayasoke kankan. Bi wọn ba si kofiri ẹni ti irin rẹ ko mọ tabi to mu ifura dani, ki wọn tete sọrọ iru ẹni bẹẹ fun ikọ agbofinro tijọba gbe kalẹ fun eyi, ki wọn le tete da sẹria to yẹ fẹni to fẹẹ da wahala silẹ naa.

Leave a Reply