David to binu luyawo ẹ pa l’Ajah ti wa lakolo ọlọpaa

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, ni ọdaran baale ile kan, David Idibie, wa bayii, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fibilu lu iyawo ẹ, Abilekọ Juliana Idibie, ẹni ọdun mejilelogoji, lalubami, tẹmi fi bọ lara ẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niṣẹlẹ buruku naa waye, nile kan ti tọkọ-taya naa n gbe ni Opopona Joado, Oke-Ira Nla, l’Ajah.

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣe f’ALAROYE nipa iṣẹlẹ ọhun, o ni iwadii fihan pe latọwọ irọlẹ ọjọ naa lawọn ololufẹ meji naa ti n fa wahala lori ọrọ kan, awọn alajọgbele wọn si lawọn o ba wọn da si i tori ọrọ lọkọ-laya lọrọ ọhun.

Wọn ni ọwọ alẹ ọjọ naa ni ariyanjiyan naa dija, ni baale ile yii bẹrẹ si i ki iyawo ẹ ni bẹndẹ gidi, o tun fibinu ti i danu, lobinrin naa ba fori sọ iganna, lo ba keboosi, o si ṣubu lulẹ.

Ṣugbọn kaka ki David ṣaajo iyawo ẹ, niṣe ni wọn lo fi i silẹ nibi to ṣubu si, to si lọọ jokoo sẹyinkule ile wọn, o ni bobinrin naa ba le ku, ko ku. Awọn alajọgbele wọn to gbọ bobinrin naa ṣe keboosi ni wọn sare lọ sibi to ṣubu si, ti wọn si gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi, ibẹ ni wọn ti sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa ti jade laye.

Bi afurasi ọdaran naa ṣe gbọ pe iyawo toun n ba ja ti doloogbe, o fẹẹ sa lọ, ṣugbọn awọn gende to wa nibẹ le e mu, wọn si pe awọn ọlọpaa lori aago, kia lawọn agbofnro lati teṣan Langbasa ti debẹ, ti wọn fi pampẹ ofin gbe David lọ sahaamọ wọn, wọn si gbe oku Juliana lọ si mọṣuari ileewosan ijọba fun ayẹwo awọn oniṣegun.

Lati teṣan naa ni wọn ti fi ọkọ iyawo yii ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ṣe paṣẹ. Alukoro ọlọpaa ni iwadii lawọn n duro de, laipẹ lawọn maa taari David siwaju adajọ, ko le gba idajọ to tọ si i.

Leave a Reply