Dele ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oogun owo loun fẹẹ fi pata obinrin toun mu ni Warewa ṣe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni kete tawọn ọlọpaa ba pari ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii ti wọn n ṣe lori Dele Ọpẹ, fọganaisa ẹni ọdun mejilelogun to ji pata obinrin ni Warewa, nipinlẹ Ogun, lati fi ṣoogun owo ni yoo foju bale-ẹjọ gẹgẹ bi CP Kenneth Ebrimson ṣe sọ.

Obinrin kan ni taya mọto rẹ jo nigba to fẹẹ jade, n lo ba ranṣẹ pe Dele, fọganaisa to wa nitosi ẹ ni Warewa, lopin ọsẹ to kọja.

Dele ṣe taya tan, o ba tiẹ lọ. Ṣugbọn gẹrẹ to lọ tan ni obinrin to gbeṣẹ fun un ri i pe pata oun toun sa sori okun ti poora.

Ko sẹlomi-in ninu ile naa pẹlu obinrin yii, gẹgẹ bi alaye to ṣe fun wọn ni teṣan ọlọpaa Warewa to mu ẹjọ naa lọ.

Obinrin naa ṣalaye pe ẹnikan ṣoṣo to wọnu ọgba oun wa naa ni fọganaisa yii, bo si ṣe lọ tan loun ko ri pata toun sa sori okun mọ.

DPO Fọlakẹ Afẹnifọrọ ko foju kekere wo keesi naa, kia lo ni kawọn ọlọpaa lọ sile Dele, ki wọn tu ibẹ wo yẹbẹyẹbẹ boya wọn yoo ri pata naa. Afi bi wọn ṣe dele Dele loootọ ti wọn ba pata alawọ Elese-aluko (purple) ti wọn n wa, bi wọn ṣe mu fọga niyẹn.

Nigba to n ṣalaye ohun to jẹ ko ji pata ka, Dele sọ pe oogun owo loun fẹẹ fi i ṣe. O ni babalawo oun lo ni koun wa pata obinrin wa.

Ni bayii,ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti ni afi ki wọn gbe e de kootu, ko si gbọdọ pẹ rara.

Leave a Reply