Dẹrẹba danfo la ọmọ-odo mọ oṣiṣẹ LASTMA lori l’Ekoo

Adeounmu Kazeem

Teṣan awọn ọlọpaa ni ọkunrin ọmọ Ibo kan ti n sẹju pakopako bayii lẹyin ti awọn ẹṣọ agbofinro ojupopo l’Ekoo, LASTMA, ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lori ẹsun wi pe o fẹẹ fi ọmọ-odo lu ọkan lara awọn oṣiṣe awọn pa.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Jakande Estate, lojuna Eko si Ẹpẹ, ni wahala buruku ti bẹ silẹ laarin oṣiṣẹ LASTMA, Kosoko Razak, ati ọkunrin awakọ ero kan, Fred Onwuche. Ọmọ odo ni wọn sọ pe awakọ yii fa yọ, to si la a mọ ọkunrin ẹṣọ agbofinro ọhun lori.

ALAROYE gbọ pe mọtọ ero kan ti nọmba idanimọ ẹ jẹ AAA 693 YC, ni Fred wa lọjọ naa, ati pe ohun to da wahala silẹ laarin wọn ko ju bi ọkunrin yii ko ṣe lo bẹliiti ọkọ bo ti ṣe wa nidii ṣiarin, nigba to n wa mọto, eyi to mu Razak sọ pe o ti lufin irinna ọkọ wiwa l’Ekoo.

Wẹrẹ bayii ni wọn sọ pe wahala ọhun bẹrẹ, nigba ti awọn eeyan yoo si fi ri i, niṣe ni Fred la ọmọ-odo mọ osiṣẹ LASTMA lori, n lọrọ ba di bami-in mọ ọn lọwọ.

Ọga agba fun ajọ LASTMA, Ọlajide Oduyọye, ti bu ẹnu atẹ lu ohun ti dẹrẹba yii ṣe, bẹẹ lo ti fidi ẹ mulẹ wi pe o ti di dandan ki ọkunrn naa foju winna ofin.

Oduyọye fi kun pe, “Bi ọkunrin yii ṣe kọlu oṣiṣẹ LASTMA lọjọ yẹn, ko si aniani kankan, bi ẹni to fẹẹ mọ-ọn-mọ pa a ni, idi ẹ niyẹn ti a ṣe gbọdọ fi ọkunrin yii jofin, ki awọn mi-in bii tiẹ ti wọn ba tun fẹẹ kọlu awọn ẹṣọ agbofinro wa le ro o lẹẹmeji ki wọn too ṣe e. Ọlọrun gan an lo sọ pe Ọgbẹni Razak ko ni i ku mọ ọn lọwọ, nitori o mọ-ọn-mọ fẹẹ pa a danu ni.

“Iru awọn eeyan bii awakọ yẹn pọ daadaa ti wọn maa n kọlu awọn oṣiṣẹ LASTMA, aimọye awọn eeyan wa ni wọn ti pa danu bẹẹ, ṣugbọn eleyii ti ọwọ tẹ yii gbọdọ sọ ohun to ri lọbẹ, to fi waaro ọwọ”

Teṣan ọlọpaa to wa ni ilu Ilasan, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa l’Ekoo, ni Onwuche wa bayii, ibẹ naa lo maa gba dele ẹjọ

 

Leave a Reply