Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago marun-un kọja ogun iṣẹju ni dẹrẹba awakọ danfo kan pade iku ojiji, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti tirela to ko okuta ṣubu le e lori loju ọna marosẹ Eko s’Abẹokuta, lagbegbe Too-Geeti, ni Sango-Ọta.
Ko sohun to fa ijamba yii bi Kọmandanti Ahmed Umar ti i ṣe ọga FRSC Ogun ṣe wi ju pe awakọ to wa tirela naa n wa iwakuwa, ohun to fa a to fi lọọ pa ẹni ẹlẹni to n wa danfo ẹ lọ jẹẹjẹ niyẹn.
Nọmba to wa lara tirela naa ni LND 634 YE, ti bọọsi akero si ni FST 744 YD.
Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ gan-an, Umar sọ pe ilu Eko ni tirela ti n bọ, Sango-Ọta lo si n lọ. O ni nigba to de Too-geeti lo ṣubu le danfo naa lori.
Dẹrẹba to n wa danfo yii nikan lo wa ninu ọkọ naa, ẹsẹkẹsẹ lo si dagbere faye nigba ti tirela ti tẹ ẹ pa mọnu danfo naa.
Mọṣuari to wa ninu ọgba ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn gbe oku dẹrẹba naa lọ.
Ohun tawọn eeyan n sọ nipa iṣẹlẹ yii ni pe ki i ṣe pe awakọ to wa tirela n wa iwakuwa, wọn ni ọna ni ko daa.
Ọpọ eeyan n sọ pe ko sẹni ti ko mọ pe ọna yii buru jai, ijọba ko si ti i tun un ṣe to lati dẹkun ijamba, wọn ni ohun to fa a ti tirela fi wo paayan niyẹn.