Dẹrẹba fi mọto gbe iyaale ile kan, lo ba lọọ fipa ba a lo pọ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọgba ẹwọn ni derẹba kan, Gboyega Ogunlọla, ẹni ọgbọn ọdun, wa bayii niluu Ado-Ekiti, nitori wọn ni o fipa ba iyawo oniyawo to wọ mọto rẹ sun, o lu u bii ẹni lu bara lẹyin ibasun naa, o si tun gba owo lọwọ obinrin naa ati foonu rẹ pẹlu.

Alaye ti obinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa ṣe fawọn ọlọpaa ni pe ipinlẹ Anambra, nibi tawọn ọmọ oun ti n kawe, loun n lọ lọjọ naa lati Ekiti, oun si wọ mọto Gboyega ti i ṣe ọkọ ayọkẹlẹ.

O fi kun alaye ẹ pe lọgan ti oun wọnu mọto naa ni dẹrẹba yii fi kinni kan wọ oun loju lati oke sisalẹ, oorun si bẹrẹ si i kun oun lẹsẹkẹsẹ. Obinrin naa ni titi to fi gbe oun dele rẹ, oun ko mọ. O ni ninu ile naa lo ti fipa ba oun lo pọ.

Lẹyin ibalopọ naa, o lo tun lu oun bii ẹni lu bara, o si gba ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) toun fẹẹ lọọ fi sanwo ileewe awọn ọmọ oun l’Anambra lọwọ oun, ati foonu toun n lo. Ọsibitu loun si balẹ si lẹyin lilu to lu oun naa.

Nigba ti awọn ọlọpaa gbe afurasi yii dele-ẹjọ lọsẹ to kọja, Agbefọba Olubu Apata, sọ pe gbogbo iwa ti olujẹjọ hu yii lodi sofin, ijiya si wa fun un labẹ ofin.

O rọ kootu pe ki wọn jẹ ki dẹrẹba yii wa latimọle na, titi digba ti imọran yoo fi wa latọdọ DPP to n gba kootu nimọran.

Adajọ Sala Afunṣọ paṣẹ pe ki Gboyega Ogunlọla ṣi wa lọgba ẹwọn titi di ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.

Leave a Reply