Dẹrẹba ileewe pamari fipa ba ọkan ninu awọn akẹkọọ to n gbe lọ sileewe lo pọ l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Fun pe o fipa ba ọmọbinrin ti ọjọ ori ẹ ko ju mẹrin lọ lo pọ, dẹrẹba kan torukọ ẹ n jẹ Humble Micheal, ti wa lẹka to n ri si ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe nipinlẹ Ogun bayii, ibẹ ni yoo si gba dele ẹjọ.

Mọto ti wọn fi n gbe awọn ọmọ lọ sileewe ti wọn si tun fi n gbe wọn pada sile awọn obi wọn ni Micheal n wa nileewe kan ti wọn forukọ bo laṣiiri, l’Ogijo, nipinlẹ Ogun.

Lọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, lo mu ọkan ninu awọn ọmọ to n gbe lọ sile gun bii ewurẹ, ko wo ti pe ọmọ ọdun mẹrin pere lọmọ naa, bẹẹ, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36) loun.

Dẹrẹba yii ba ọmọde naa lo pọ, gẹgẹ bo ṣe funra ẹ jẹwọ lẹyin tọwọ ba a lọjọ keji iṣẹlẹ yii. Ko tilẹ sẹni to mọ pe nnkan ti ṣe lara ọmọ naa, afi nigba ti baba rẹ n wẹ fun un lọjọ keji, tori pe niṣe ni ẹjẹ n jade ṣuruṣuru loju ara ọmọdebinrin ọhun, nigba naa ni baba beere pe ki lo ṣe e labẹ, ọmọ naa si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si i.

Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ yii ṣọwọ si ALAROYE ṣe ṣalaye, o ni ọmọdebinrin naa sọ fun baba rẹ pe gbogbo ọmọ to wa ninu mọto lọjọ kọkanlelogun naa ni dẹrẹba gbe dele awọn obi wọn niṣoju oun, oun nikan loun ṣẹku to fẹẹ gbe pada sile gbẹyin.

O ni ṣugbọn bawọn ṣe n lọ lo paaki ọkọ naa sibi kan, to si fi kinni abẹ ẹ si toun.

Ohun tọmọ sọ yii lo mu baba rẹ lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Ogijo, ti CSP Muhammed Sulaiman ti i ṣe DPO ibẹ si ran awọn eeyan rẹ lati mu afurasi awakọ naa wa.

Nigba tawọn ọlọpaa fọrọ wa a lẹnu wo, ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ ọdun mẹrin yii laṣepọ, oun ba a sun bii pe agbalagba ni.

Wọn gbe ọmọ naa lọ sọsibitu, ayẹwo si fi han pe ọkunrin ti ba a ṣe, wọn ti gba òdòdó obinrin to yẹ ko wa labẹ rẹ kuro.

Kia ni wọn ti gbe Micheal lọ sẹka ti yoo ti ṣalaye ara ẹ, ti wọn yoo si ti gbe e lọ sile-ẹjọ. Bakan naa ni CP Edward Ajogun rọ awọn obi lati maa mojuto awọn ọmọ wọn daadaa, paapaa awọn ọmọbinrin, nitori awọn ikooko to da aṣọ eeyan bora bii Humble Micheal yii wa ṣi ku lawujọ wa.

Leave a Reply