Dẹrẹba muti yo, lo ba lọọ para ẹ danu sori biriiji ẹlẹsẹ l’Oṣodi

Faith Adebọla, Eko

Ọpọ eeyan to ri ijamba ọkọ to ṣẹlẹ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹnu ya, ti wọn si n beere pe kin ni mọto ayọkẹlẹ yii le wa gun ori biriiji ẹlẹsẹ lọ, to si ṣe bẹẹ pa eeyan kan, tawọn mẹta si tun fara pa yanna yanna.

Ori biriiji ẹlẹsẹ to wa lagbegbe Ṣogunlẹ, lori titi marosẹ Oṣhodi si Iyana-Ipaja nijamba naa ti waye.

Ọgbẹni Abass to ba ALAROYE sọrọ lori isẹlẹ yii sọ pe oun wa nibi iṣẹlẹ naa, o ni Ọlọrun lo yọ oun atawọn tawọn jọ duro sibudokọ Shogunlẹ lasiko naa. O ni ere buruku ni mọto ayọkẹlẹ Mazda naa n sa bọ, ko too ya kuro loju ọna.

“Iyalẹnu nla gbaa lo jẹ, ti ko ba ṣoju mi ni, mi o ni i gbagbọ, tori ọpọ eeyan to debẹ lo n beere pe bawo lọkọ yii ṣe ṣee. O da bii pe oorun kun awakọ naa lori ere ni, oun nikan lo wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa, oun nikan naa lo si ku, bo tilẹ jẹ pe mọto naa ṣe awọn mẹta to n rin lọ lori biriiji naa leṣe.

“Ọpẹlọpẹ awọn irin ti wọn fi ṣe idaabobo fawọn to n gun biriiji naa tori irin yii lo da mọto naa duro, ti ko jẹ ko tun ja bọ le awọn eeyan to duro sisalẹ lori, nigba to takiti, to ha sara irin naa loke biriiji”

Abass ni nigba tawọn alaaanu kan fi maa fi tipatipa yọ oloogbe naa jade, niṣe ni ọti lile n run lara ẹ, to fi han pe o ti muti yo pẹlu bo ṣe n wakọ.

A gbọ pe meji ninu awọn to fara pa naa ti wa nileewosan aladaani kan nitosi, nigba ti ẹni kẹta ti lọ sile ẹ lati lọọ toju ara ẹ.

A pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lori aago lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn SP Olumuyiwa Adejọbi sọ pe oun o ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply