Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ni nnkan bii aago mejila ọsan ku iṣẹju meje Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, tawọn eeyan n ṣajọyọ ọdun ominira lawọn eeyan meji kan pade iku ojiji labule Awowo, loju ọna marosẹ Eko s’Abẹokuta. Dẹrẹba to wa mọto wọn lo sare asaju ti mọto fi gbokiti, ti wọn fi di ara ọrun dipo ilu Abẹokuta ti wọn n lọ.
Awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn sọ pe ere buruku ni dẹrẹba to wa mọto naa n sa, bẹẹ naa si ni Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, nipinlẹ Ogun, ṣe fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Akinbiyi sọ pe eeyan mẹjọ lo wa ninu mọto naa, obinrin mẹfa ati ọkunrin meji. O ni ere ti dẹrẹba naa sa wọ aarin kan to daagun lo fa wahala, ibẹ ni ọwọ rẹ ko ti ka mọto naa mọ́, bi mọto ṣe gbokiti niyẹn ti ọkunrin ati obinrin kan si ku lẹsẹkẹsẹ ninu awọn ero ọkọ naa.
Dẹrẹba to n sare asapajude yii ko ku gẹgẹ bi Akinbiyi ṣe wi, o kan fara pa ni.
Mọṣuari to wa ninu ọgba ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn ko awọn oku mejeeji si, wọn si gbe awọn ti wọn farapa lọ si Ọsibitu Jẹnẹra Ijaye, l’Abẹokuta.
Bawọn TRACE ṣe ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun ni wọn n kilọ fawọn awakọ pe ki wọn yee sare buruku loju popo mọ, paapaa lasiko yii tojo n rọ.
Bakan naa ni wọn ni kawọn awakọ maa fẹsọ wọ kọna tabi iyana, nitori awọn ibi to ba ri bẹẹ ko ṣee maa sare wọ bi wọn ko ba fẹ ki iru ijamba bayii maa waye.
Caption