Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Eyo Eta lọkunrin ti ẹ n wo fọto rẹ yii n jẹ, iṣẹ dẹrẹba lo n ṣe lọdọ Ọmọpariọla, nipinlẹ Eko. Afi bo ṣe gbe mọto ọga ẹ kuro l’Ekoo lai sọ fun un, Benin lo fẹẹ ji mọto naa gbe lọ kawọn ọlọpaa too mu un nigba to de Ìjẹ̀bú-Imuṣin, nipinlẹ Ogun.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji yii, lọwọ ba Eta pẹlu mọto Toyota Highlander to ni nọmba APP 467 GS, eyi ti i ṣe ti ọga rẹ.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ni ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ọlọpaa to n ṣọ ọna marosẹ da dẹrẹba yii duro nikorita Imeri, n’Ijẹbu Imuṣin.
Nigba ti wọn beere awọn nnkan kan lọwọ rẹ ti ko le dáhùn ni wọn ni yoo ba awọn de teṣan.
Teṣan lọkunrin naa ti jẹwọ pe niṣe loun fẹẹ ji mọto ọga oun gbe sa lọ si Benin.
O lọgaa oun ko mọgba toun gbe mọto rẹ jánà, nitori oun ko dagbere fun un.
Nigba tawọn ọlọpaa pe ọga Eta lori foonu, o ni dẹrẹba yii gbe mọto oun sa lọ lati Eko ni. Ọmọpariọla sọ pe oun ti fi ẹjọ rẹ sun lọdọ awọn ọlọpaa nigba toun ko ti ri i.
Wọn ti taari dẹrẹba naa si ẹka ìwadìí lẹkun-un-rẹrẹ.