Didoju ija kọ awọn agbebọn wọnyi le da ogun ẹsin ati ẹlẹyamẹya silẹ-Gumi

Faith Adebọla

Pẹlu bi gbogbo aye ṣe n kerora lori ọṣẹ tawọn janduku agbebọn n ṣe kaakiri orileede yii, ti ọpọ si n ṣadura pe k’Ọlọrun ba wọn dẹkun awọn ẹniibi afẹmiṣofo ọhun, gbajugbaja olukọ ẹsin Islam l’Oke-Ọya nni, Sheikh Ahmad Gumi, ni ko sohun to jọ ọ, kẹnikẹni ma lero pe awọn janduku apamọlẹkun-jaye maa kasẹ nilẹ yii, o ni awọn ologun kan n ṣe lasan ni, wọn o le fi ọgbọn ogun ati akọlu ṣẹgun awọn janduku naa.

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, ni Gumi sọrọ yii lori ikanni fesibuuku rẹ to maa n lo, ninu apilẹkọ kan to pe akọle rẹ ni: “Akọlu to waye ni Zamfara: Wahala ṣẹṣẹ bẹrẹ ni,” o ni bawọn ṣọja ṣe bẹrẹ si i ṣakọlu sawọn ajinigbe agbebọn yii tubọ maa fọ gbogbọ nnkan loju pọ ni, ko si le mu eeso rere kan jade, tori iṣoro aabo yii maa maa buru si i ni.

Ni ibẹrẹ ọrọ rẹ, ẹsẹ kewu latinu Kuraani lo fi bẹrẹ, o si sọ itumọ rẹ pe: “Nigbakuugba ti ina ogun ba ti n ru tuu, Allah lo le pana ẹ, ṣugbọn alabosi lọmọ araye, Allah si koriira alabosi.”

Gumi pitan pe nigba ti ipinlẹ Zamfara buwọ lu ofin Sharia lọdun 2000, tijo-tayọ lawọn eeyan fi tẹwọ-gba a, ko si wahala awọn agbebọn ati janduku, igba tijọba kọrọ oṣelu bọ ofin Sharia ni ijangbọn bẹrẹ nipinlẹ naa, to si n tan de gbogbo ilẹ Oke-Ọya, bẹẹ ni ipinlẹ Zamfara ti i ba jẹ awokọṣe rere nibi ti ibalẹ ọkan, alaafia iba ti gbilẹ di ojuko awọn oniwa ọdaran, awọn ajinigbe, ti aifararọ si gbode nibẹ.

Gumi ni nigba ti yoo fi di ọdun 2009, iwa jiji maaluu gbe ti bẹrẹ si i gbilẹ, ọpọ maaluu ti wọn ji gbe ọhun, ilẹ Yoruba ati Ibo ni wọn n lọọ ta wọn si, jiji maaluu gbe yii sọ ọpọ awọn olokoowo maaluu ati awọn darandaran di ẹdun arinlẹ, lo ba di pe awọn kan lara wọn bẹrẹ si i di janduku, paapaa nigba ti wọn bẹrẹ si i lo egboogi oloro, nigba ti yoo si fi di ọdun 2015, iwa janduku ti yipada si ti ifẹmiṣofo, lati ọdun 2019 ni wọn ti jagbọn ijinigbe, ọpọ owo ti wọn si ri gba ni wọn fi n ra nnkan ija ati ounjẹ fun ara wọn lati rọpo maaluu wọn ti wọn ti padanu sẹyin.

“Ẹ jẹ ka sọ ododo ọrọ fun ara wa, awọn darandaran wọnyi o nibikan i lọ, wọn ti gẹgun ija, wọn si ti mura ogun, wọn mọ awọn ọmoogun wa daadaa, didoju ija kọ wọn ko le seso rere kan, o maa ba nnkan jẹ si i ni. Ọrọ to gbẹgẹ gidi lọrọ to n ṣẹlẹ yii, pẹlẹtu, ọgbọn ẹwẹ, leeyan le fi yanju ẹ. Ootọ ibẹ ni teeyan ba ti gba ki aladuugbo ẹ mu oun lọtaa, oluwaẹ ti wa ninu ewu niyẹn.

“Ẹ ranti pe nigba wahala ENDSARS, igbesẹ ologun tubọ fọ gbogbo nnkan loju pọ ni. Didoju ija kọ awọn agbebọn wọnyi maa tubọ polukurumuṣu ọrọ ni, o si le bi ogun ẹsin ati ẹya silẹ. Ko sibi ti wọn ti n lo ọgbọn ijagun lati ṣẹgun awọn eeṣin-o-kọku yii, o si yẹ ki ọrọ awọn Taliban to gbajọba ni Afghanistan laipẹ yii kọ wa lọgbọn. Emi wi temi o.”

Bayii ni Gumi pari ọrọ rẹ.

Leave a Reply