‘Diẹ lo ku ki awọn Amọtẹkun fibọn fọ mi lori n’Ibadan’

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bi ọrọ ti ayaworan kan n’Ibadan atawọn eeyan kan nigboro ilu naa sọ ba jẹ oootọ, afaimọ nijọba ati gbogbo araalu ko ni i pada kabaamọ lori ọrọ Amọtẹkun, ikọ eleto aabo ti awọn ijọba iha Iwọ-Oorun Guusu orileede yii da silẹ lati fopin si ijinigbe, idigunjale ati ipenija eto aabo gbogbo nilẹ nilẹ Yoruba.

Gbajugbaja ayaworan to filu Ibadan ṣebugbe sọ pe diẹ lo ku ki awọn ikọ eleto aabo naa fi ibọn fọ oun lori lai ṣẹ, lai ro, nigboro ilu naa l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ọkunrin to pera ẹ ni @hifee_nonii lori ikanni abẹyẹfo (twitter) rẹ, ṣalaye pe nigba ti oun n bọ lati ṣọọṣi ni nnkan bii ago mejila ọjọ Tusidee loun ri  awọn eeyan ti wọn n sa gilagila lai mọ ohun to n le wọn.

O ni oun ko ti i pẹ rara nibi ti oun wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ oun ti oun fi mọ pe awọn ikọ Amọtẹkun ni wọn n sa fun, ati pe ka sọ toootọ, niṣe loju awọn eeyan naa le koko lagbari wọn bii jagunjagun to n lọ soju ogun.

Baba ayaworan yii sọ siwaju pe loju oun bayii lawọn Amọtẹkun fi yinbọn mọ ọkunrin kan to n jade bọ lati ibi to ti lọọ ṣegbọsẹ ninu igbo. Ṣugbọn Ọlọrun yọ ọkunrin naa, ibọn ko ba a.

Niwọn igba ti oun ko ti lẹbọ lẹru, ti oun ko si huwa ọdaran kankan, ọkunrin ti awọn ololufẹ ẹ lori ẹrọ ayelujara mọ si @hifee_nonii yii sọ pe oun mọ-ọn-mọ din ere to yẹ ki oun fi ọkọ sa ku ki oun le ribi woran ohun to n ṣẹlẹ daadaa.

Iran ti onifọto yii n wo ko tẹ awọn Amọtẹkun lọrun, n lọkan ninu wọn ba pariwo mọ ọn pe ko kọri sibi to n lọ kia. Iyẹn fesi pe nitori ọna ti ko daa ni ko jẹ ki oun sare, idahun yii lo si bi wọn ninu ti wọn ṣe fa ibinu yọ si i.

Ọkunrin onifọto yii sọ siwaju pe lẹyin ti awọn Amọtẹkun beere iru iṣẹ ti oun n ṣe, ti oun si fun wọn lesi pe ayaworan loun, ni wọn yẹ inu mọto oun wo finnifinni. Toun ti bi wọn ko si ṣe ba ẹru to lodi sofin tabi mu ifura dani kankan nibẹ to, niṣe lọkan ninu wọn tun jagbe mọ oun lati tete maa sare lọ bi oun ko ba fẹ ki oun fibọn fọ ori oun danu.

Eyi lo mu ki ọkunrin yii fẹjọ awọn Amọtẹkun sun ijọba ipinlẹ Ọyọ, o ni pẹlu iwa ti wọn n hu yii, afaimọ ni iwa ọdaju ati ijanba ti awọn paapaa yoo maa hu sawọn araalu gan-an ko ni i buru kọja eyi ti diẹ ninu awọn ọlọpaa SARS hu ti awọn ọmọ Naijiria fi fẹnu le wọn lọ.

Ṣaaju lawọn olugbe adugbo Isalẹ-Osi, n’Ibadan, ti ṣalaye iwa ọdaju tawọn Amọtẹkun n hu lagbegbe wọn fakọroyin wa, wọn ni ọrọ ti ko to nnkan ni wọn maa n fiya jẹ awọn si, wọn si fẹ́ẹ̀ le mu eeyan to ṣeeṣi fẹgbẹ gba wọn tabi tẹ wọn mọlẹ loju titi lasan ni ìmú ọdaran.

 

Wọn waa rọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde lati ba awọn Amọtẹkun sọrọ, ki afojusun ijọba lori idasilẹ wọn ma baa ja sasan.

Leave a Reply