Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin agbẹ kan, Gbenga Adebayọ, lori ko yọ lọwọ awọn Fulani kan to fẹẹ ji oun atawọn aburo rẹ gbe loju ọna oko wọn lagbegbe Ajagbusi, Àlà, eyi to wa nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.
Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lori ohun to foju wina latọdọ awọn ajinigbe ọhun lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye, Gbenga ni oko loun atawọn aburo oun kan n lọ lọjọ naa ti awọn Fulani mẹrin fi da awọn lọna, ti wọn si ko awọn wọnu igbo kijikiji lọ.
O ni awọn ko ti i rin jinna lọ titi ti awọn fi mọ pe awọn ti ko ṣọwọ awọn agbebọn to ji awọn gbe.
Gbenga ni lẹyin tawọn ti rin fun wakati diẹ ti oun si ṣakiyesi pe aaye diẹ wa laarin awọn atawọn Fulani ọhun loun ki awọn aburo oun laya, ti oun si jẹ ko ye wọn pe wọn gbọdọ ṣọkan akin, ki awọn le fi igboya gba ara awọn silẹ lọwọ awọn agbebọn mẹrẹẹrin to n ko awọn wọnu igbo lọ.
Ọmọkunrin yii ni bi awọn ṣe ki ere mọlẹ ti awọn fẹẹ maa sa lọ, awọn ko mọ pe awọn ajinigbe naa n ṣọ awọn lọwọ lẹsẹ bi awọn ti n lọ. Niṣe ni wọn sun mọ oun ti wọn si n ṣa oun ladaa kíkankíkan.
Ọkunrin to yan iṣẹ agbẹ ṣiṣe laayo ọhun ni oun ko fi bẹẹ kọbi ara si ada ti wọn n ṣa oun rara, ọna bi yoo ṣe jajabọ, ti yoo si gba ara rẹ silẹ lọwọ awọn ajinigbe naa lo ni o gba ọkan oun ni gbogbo asiko ti awọn jọ fi wọya ija. O ni oun gbiyanju titi ti oun fi raaye sa mọ wọn lọwọ, bo tilẹ jẹ pe loootọ loun fara pa pupọ, ti oun si tun ti padanu ọpọlọpọ ẹjẹ.
Odidi ọjọ meji lo ni oun fi wa nibi ti oun subu si ninu igbo lẹyin ti oun jaja bọ tan, ki awọn alaaanu kan too doola ẹmi oun, ti wọn si gbe oun wa si ọsibitu, nibi ti oun ti n gba itọju lọwọ.
Gbenga waa n bẹ awọn araalu lati dide iranlọwọ fun oun, nitori ọpọlọpọ iṣẹ abẹ ni wọn ṣi fẹẹ ṣe fun oun nileewosan ti oun wa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni loootọ lawọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ti igbesẹ si ti n lọ labẹnu lati ri awọn janduku naa mu laipẹ.