Diẹ lo ku ki n para mi nigba kan, orin l’Ọlọrun fi doola ẹmi mi – Ọọni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, ti ṣapejuwe orin gẹgẹ bii ohun  kan gboogi to lagbara ninu igbe-aye ọmọniyan, to si jẹ ẹbun to dara ju lọ lati ọdọ Ọlọrun si iran eniyan lọjọkọjọ.

Kabiesi ṣalaye pe igba kan wa ti oun pinnu lati pa ara oun, ṣugbọn lẹyin ti oun gbọ oniruuru awọn orin ẹmi loun yi ipinnu buburu naa pada.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita lo ti sọ pe ni The Muson Centre, to wa niluu Eko, ni Ọọni Ogunwusi ti sọrọ naa lasiko iṣide ayẹyẹ kan ti wọn pe ni ‘Memorable Moments With Music’, alakọọkọ iru ẹ.

Kabiesi sọ pe, “Akoko to ga ju fun mi leleyii. Agbara wa ninu orin. Nigba ti mo fẹẹ para mi lasiko ti mo n ṣiṣẹ tale-ralẹ kaakiri, orin lo doola ẹmi mi. Ọna ibasọrọ pẹlu Ọlọrun ni orin jẹ.

“Mo tete rọwọ mu ninu iṣẹ ka tale-ralẹ. Mo ya biliọnu lọna mẹjọ lọdun bii mejila sẹyin lati fi kọ ile alaja pupọ kan, ṣugbọn nigba ti a gbe e de ipele kẹwaa ni mo ni lati wo o lulẹ funra mi, gbogbo owo si wọgbo bẹẹ.

“Gbogbo nnkan dorikodo, ọna abayọ kan ṣoṣo ti mo si ni ni ki n pokunso, ṣugbọn nigba ti mo gbọ oniruuru awọn orin-ẹmi, ọpọlọ mi pe pada lati mọ pe ireti ṣi n bẹ niwọn igba ti ẹmi ba wa.

“Latigba yẹn ni mo ti n lo orin gẹgẹ bii ohun eelo agbara to n yanju gbogbo ipenija ti mo ba koju, mo si pinnu pe ma a ko owo le ori orin atawọn nnkan to le pese iṣẹ fun awọn ọdọ ati awọn to ku diẹ ka a to fun lawujọ.

“Ẹyin eniyan mi, ohunkohun ti ẹ ba n la kọja, ẹ dakun, ẹ ma ṣe sọ ireti nu. Ẹ lo orin ẹmi lati fi ru ọkan yin soke.”

Ọọni fi kun ọrọ rẹ pe oun ni ajọṣepọ pẹlu oniruuru awọn ẹgbẹ akọrin bii Akọrin Oodua, Emerald Choir, niluu Akurẹ, Bethesda Home for the Blind, Lagos, UNILAG Choral, Xplicit Dancers, Ibadan

Lara awọn ti wọn mu ki eto naa kẹsẹjari ni Ekemini Theatre Troupe, Oghene Umu-Africa (Children of Africa), Team Definition, Kenny Blaq, Bisọla Ọmọge Bata atawọn mi-in.

Leave a Reply