Diẹ lo ku ki wọn fi lilu ran Isiaka sọrun, ewure lo ji gbe n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹṣinburuku ni wọn fi ogbologboo ole kan, Isiaka, to ji ewurẹ gbe niluu Ilọrin, ṣe lowurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹfa yii. Se ni awọn eeyan n ho gee le e lori, lẹyin ti wọn ti fi lilu da batani si i lara, ti ẹjẹ si n ṣan bala ni gbogbo ara rẹ.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Homony Estate, ni Akerebiata, ni Isiaka ti lọọ ji ẹran ewurẹ gbe pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry rẹ. Bo ṣe gbe ẹwurẹ sinu ọkọ rẹ tan ni awọn eeyan kan kẹẹfin rẹ, ni wọn ba bẹrẹ si i pariwo ole le e lori. Eyi lo mu ki ọmọkunrin naa bẹrẹ si i sa lọ pẹlu ọkọ to ko ewurẹ ọhun si. Ṣugbọn awọn araadungbo ko duro, bo ṣe n sa lọ ni wọn bẹrẹ si i fi ọkada le e lọ. Bi Isiaka ṣe n fi ọkọ rẹ kọ lu awọn eeyan loju ọna lo n kọ lu awọn ọlọkada, ko le baa raaye sa mọ wọn lọwọ. Wọn ni ọpọ awọn eeyan to ti kọ lu ni wọn ṣi wa nileewosan bayii.

Ọkọ akero Siena kan ni Isiaka kọ lu lagbegbe Òkèkeere, ti ọkọ tiẹ naa fi bajẹ, ti ko si le lọ mọ tọwọ fi tẹ ẹ.

Wọn wọ Isiaka bọọle ninu ọkọ rẹ, ni wọn ba ni ko maa rin niṣo ni Akerebiata to ti jale, bẹẹ ni obitibiti ero n rọ tẹle e lati agbegbe Òkèkeere, de Ọmọ́dá, Òde-Aláúsá, Ìdí-Àpẹ́, ti wọn fi de agbegbe Ìta-Adú, nibi ti wọn fẹ pa a si.

Awọn ọdọ yii si lu ọmọkunrin naa nilukulu debii pe ẹmi ti fẹẹ bọ lkara rẹ. Awọn ọlọpaa to de sasiko lo gba Isiaka silẹ lọwọ awọn ọdọ yii.

Awọn agbofinro yii lo gbe Isiaka lọ si ileewosan fun itọju.

Leave a Reply