Faith Adebọla
Pẹlu atẹwọ, ijo ati idunnu ni oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, fi tẹwọ gba olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Ọnarebu Yakubu Dogara, ti wọn si ki i kaabọ sinu ẹgbẹ oṣelu naa, bo ṣe n dagbere fun APC.
Nibi ayẹyẹ eto ipolongo ibo funpo aarẹ Atiku, eyi to waye niluu Eko ni iṣẹlẹ yii ti waye.
Dogara, to ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ APC nigba to fi wa nipo olori aṣofin, to tun pada sinu ẹgbẹ PDP lẹyin naa, ko too pada sinu APC nigba to ya, fẹnu ara ẹ kede pe oun ti digba-dagbọn oun wayi, oun ko ṣe APC mọ, PDP loun n ba lọ.
Afi bii ẹni pe wọn ti n reti ọkunrin naa tẹlẹ, Dogara fẹrẹ ma ti i kuro ninu APC tan ti wọn fi yan an gẹgẹ bii ọmọ igbimọ ipolongo ibo aarẹ fun Atiku Abubakar.
Ninu atẹjade kan ti Alakooso agba fun igbimọ ipolongo naa, to tun jẹ Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal fi lede lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla yii, o ni iyansipo Dogara bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ ni, ko si lọ-ka-bọ ninu ẹ.
Tambuwal ni, “Eyi jẹ ọkan lara isapa wa lati ri i pe a fọwọ sowọ pọ, a si fi igbanu kan ṣoṣo ṣọja, lati duro bii igi lẹyin ọgba fun oludije funpo aarẹ wa, Atiku Abubakar, ka le gba orileede wa pada, ka si fẹsẹ ẹ rinlẹ lọna ti yoo fi goke agba si i.
Tẹ o ba gbagbe, Dogara, jẹ ọkan ninu awọn to lewaju ninu atako lodi si bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe fa oludije funpo aarẹ ẹlẹsin Musulumi ati igbakeji ẹlẹsin Musulumi kan naa kalẹ. Oun atawọn ẹlẹgbẹ rẹ ti lawọn o ni i kuro lẹgbẹ APC, ṣugbọn awọn o ni i ṣiṣẹ fun ẹgbẹ naa lati jawe olubori, ṣugbọn ọrọ ti bẹyin yọ bayii pẹlu bo ṣe darapọ mọ ipolongo Atiku niluu Eko.
Ọsẹ to kọja yii ni awọn agbaagba kan lapa Oke-Ọya, atawọn agbarijọpọ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni, atawọn adari ẹsin Musulumi, to fi mọ awọn eekan eekan oloṣelu kan nilẹ Hausa fi ipinnu wọn lede pe, lẹyin tawọn yiiri ọrọ to n ja ran-in yii sọtun-un sosi, ipinnu awọn ni pe Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn maa ṣiṣẹ fun, oun si lawọn maa dibo fun funpo aarẹ lọdun 2023.