Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ṣẹ ẹ ranti ọkunrin dokita kan to sin oku ọrẹbinrin rẹ ati iyaale ile mi-in sinu ọfiisi rẹ lọsibitu to ti n ṣiṣẹ niluu Ilọrin nipinlẹ Kwara. Ile-ẹjọ Majisitreeti to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo, ti paṣẹ ki wọn sọ dokita alabẹrẹ naa, Abas, Adio Adeyẹmi, to n ṣiṣẹ nileewosan Jẹnẹra ilu Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, sọgba ẹwọn Oke-Kura, fẹsun ipaniyan.
Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka tipinlẹ Kwara, lo wọ dokita alabẹrẹ naa lọ siwaju Onidaajọ Muhammad Ibrahim, fẹsun pe o pa ọrẹbinrin rẹ torukọ rẹ n jẹ Ọlanipẹkun Ifẹoluwa, to si ju oku ẹ sigbo niluu Alapa, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, Lẹyin naa lo tun pa iyaale ile kan, Nofisatu Halidu, to n ṣiṣẹ nileewosan Jẹnẹra, niluu Kaiama, to si sin oku rẹ sinu ọfiisi rẹ, wọn lo tun jẹwọ pe oun pa arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abubakar.
Agbefọba Nasir Yusuf, lo ko gbogbo awọn ẹri siwaju ile-ẹjọ nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ yii, ti adajọ si yẹ gbogbo awọn ẹri naa wo finni-finni, lẹyin naa ni Adajọ Muhammad Ibrahim, paṣẹ pe ki wọn ju dokita yii sẹwọn Oke-Kura.
O sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.