Dokita ogun lo tun lugbadi arun Korona laarin ọsẹ meji ni Kwara

[contact-form][contact-field label=”Name” type=”name” required=”true” /][contact-field label=”Email” type=”email” required=”true” /][contact-field label=”Website” type=”url” /][contact-field label=”Message” type=”textarea” /][/contact-form]

Stephen Ajagbe, Ilọrin

 

 

Aarẹ ẹgbẹ awọn Dokita, iyẹn Association of Resident Doctors (ARD), ẹka ilewosan ẹkọṣẹ fasiti Ilọrin, UITH, Dokita Badmus Habeeb, ni o kere tan, awọn dokita ogun lo tun lugbadi arun Korona laarin ọsẹ meji si mẹta lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn.

O sọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹside, ọsẹ yii, lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin.

Dokita Badmus ni ohun to n fa iru iṣẹlẹ bẹẹ ni pe iwọnba awọn ohun eelo to wa nilẹ lawọn dokita naa lo lati koju arun naa.

O ni asiko yii ko dara rara fun awọn, mọlẹbi awọn atawọn alarun Korona tawọn n tọju nitori ohun toju awọn ri lẹnu iṣẹ naa.

Dokita naa ni bi wọn ṣe gbe abẹrẹ jade lati koju arun naa ti mu ọkan awọn balẹ diẹ, awọn si nireti pe alaafia yoo wa fun gbogbo awọn to ti ko arun naa.

O ni ko daju pe orilẹ-ede Naijiria yoo ri abẹrẹ Covid-19 ra lasiko, nitori bijọba ko ṣe pese ọna to rọrun, paapaa nipa ti owo, lati ra a ni kiakia.

O ṣalaye pe iwadii ti fi han pe abẹrẹ Covid-19 naa n ṣiṣẹ daadaa, ko si si idi kankan ti ko fi yẹ ki araalu tẹle ilana to tọ lori gbigbe ogun ti arun naa.

O gba ijọba nimọran lati pese awọn ohun tawọn oṣiṣẹ ilera kaakiri orilẹ-ede Naijiria nilo ati sisan ẹtọ wọn lasiko.

Leave a Reply