Donald Trump dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria, o ni wọn wu oun lori gidi

Aderohunmu Kazeem

Aarẹ orilẹ-ede America, Donald Trump, ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori aduroti wọn, bẹẹ lo sọ pe ohun iwuri nla lo jẹ foun.

Fidio kan ti awọn ọmọ Naijiria, kan ṣe ti Aarẹ yii ri, ti wọn sọ pe awọn fi ṣatilẹyin fun un lori ibo Aarẹ to waye nilẹ America lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lọkunrin yii ri, to si dunnu si gidigidi.

Ori ikanni abẹyẹfo (Twitter) ẹ lo lọ, ti oun naa si kọ ọ sibẹ pe ‘Awọn eeyan Naijiria lo tori mi to lọwọọwọ bayii, oun iwuri nla ni’

Ninu fidio ọhun lawọn ọmọ orilẹ-ede yii kan ti to, ti wọn si n kọrin aṣeyọri fun un pẹlu ilu ati ijo. Ohun ti wọn si n sọ ni pe ti ẹgbẹ oṣelu Republican nilẹ America lọhun-un lawọn n ṣe. Pẹlu asia ilẹ America lawọn ọmọ Naijiria fi n jo, ti wọn n kọ orin idunnu fun un, ti wọn si n sọ pe oun ni yoo wọle pada gẹgẹ bii Aarẹ. Lara paali ti wọn si gbe dani naa ni wọn kọ ọ si bayii pe ‘Trump 2020’.

Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, lawọn eeyan ilẹ America jade lati dibo fẹni ti yoo ṣe olori orilẹ-ede ọhun, bẹẹ ni idije yii si waye laarin Aarẹ to wa nipo lọwọlọwọ, Donald Trump, ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ati Joe Biden, ti Democratic.

Bo tilẹ jẹ pe ilẹ America ni idibo ọhun ti waye, sibẹ, niṣe lawọn ọmọ orilẹ-ede yii paapaa fẹẹ mọ ẹni ti yoo wọle. Bẹẹ gẹgẹ ni ẹnu ko ṣọkan, bi awọn eeyan kan ṣe n fẹ Trump, bẹẹ lawọn mi-in n tẹle ẹni keji ẹ, Joe Biden.

Ọkunrin oloṣelu ọmọ ẹgbẹ PDP nni, Fẹmi Fani-Kayọde, ninu ọrọ tiẹ lo ti sọ pe, “Gbogbo aye pata loju wọn wa lara ibo Aarẹ ilẹ America, abajade ibo ọhun ko ni i ṣai ni ipa nla to maa ko ninu ọrọ agbaye fun aadọta ọdun si i, bẹẹ ni yoo tun ni ipa ninu igbe aye ẹni kọọkan ninu awọn eeyan bii biliọnu meje ati aabọ to wa laye yii. Mo gbadura ki Donald Trump tun wọle lẹẹkan si i, nitori bi awọn eeyan ilẹ America ṣe nilo ẹ lasiko yii, bẹẹ gan-an ni gbogbo agbeye nilo ẹ pẹlu.”

Leave a Reply