Donald Trump sọrẹnda, eto igbejọba silẹ ti bẹrẹ l’Amẹrika

Aderounmu Kazeem

Ni bayii, gbogbo wahala ti Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump, n fa lori bi Joe Biden ṣe wọle ninu ibo ti wọn di laipẹ yii ti fẹẹ wa sopin patapata.

Ileeṣẹ ijọba to maa n ṣeto bi eto igbejọba silẹ yoo ṣe waye nilẹ Amẹrika ti kan si Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden, pe ko maa mura silẹ, ijọba Donald Trump ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹ lori bi eto ti wọn yoo fi gbe ijọba fun un yoo ṣe waye.

Lori tẹlifiṣan CNN ni iroyin ọhun ti waye laipẹ yii gẹgẹ bi oludari ileeṣẹ to maa ri si eto igbejọba silẹ ṣe sọ ọ, iyẹn Emily Murphy.

Wọn ni lẹta yii ni yoo jẹ igbesẹ akọkọ ti ijọba Trump yoo gbe lati gba pe loootọ, Joe Biden, to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu The Democratic Party lo wọle latigba ti wọn ti dibo Aarẹ orilẹ-ede America nibẹrẹ oṣu kọkanla yii.

Lẹta yii naa ni yoo si jẹ ohun ifọwọsi pe Trump ti gba, ni kete ti Emily Murphy ba ti buwọ lu u, eyi to duro gẹgẹ bii eto ati ilana lẹyin idibo fun ẹni to ba ti jawe olubori.

Ni bayii ti ijọba Trump ti gba, lọgan ni eto yoo bẹrẹ, eyi ti yoo fun awọn to n ba ijọba Trump, ṣiṣẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ti Aarẹ tuntun, Joe Biden, fun eto igbejọba silẹ.

Wọn ti sọ pe ọpọlọpọ miliọnu owo ni ijọba Amẹrika yoo

na lori eto naa. ALAROYE gbọ pe gbogbo awọn ipinlẹ ti Aarẹ Donald Trump pe ẹjọ si ni wọn ti da ẹjọ ẹ nu bayii lori eto idibo ọhun. Koko ohun ti wọn si fi da a nu ni pe ọkunrin naa ko ri ẹri gidi kan bayii ko silẹ nipa awọn ẹjọ to pe ọhun.

Leave a Reply