DSS fẹsun afẹmiṣofo kan awọn ọmọọṣẹ Igboho meji to wa lọdọ wọn

Ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fẹsun afẹmiṣofo kan meji ninu awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho, awọn naa ni Noah Oyetunji ati Amudat Babatunde to jẹ obinrin kan ṣoṣo to wa ninu wọn.

Ẹ oo ranti pe o le loṣu meji tawọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho mejila ti wọn ko pamọ fi wa lahaamọ DSS l’Abuja, ki wọn too fi awọn mẹjọ silẹ ninu wọn lọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, ti wọn si fi awọn meji mi-in silẹ lọjọ Ẹti to kọja, ṣugbọn ti wọn kọ lati fi Noah ati Amudat silẹ.

Nigba to n ṣalaye idi tawọn meji yoo ṣi fi wa lahaamọ, agbẹjọrọ DSS, S.M Bello, sọ pe Noah Oyetunji ni awọn nnkan ija oloro to le fẹmi eeyan ṣofo lọwọ, bẹẹ ni Amudat Babatunde n polongo iwa ifẹmiṣofo loju opo Fesibuuku rẹ lori ayelujara.

Ẹsun marun-un ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ifẹmiṣofo ni wọn fi kan awọn ọmọ ẹyin Igboho meji yii.

Ṣugbọn lọọya awọn olujẹjọ,  Amofin Pẹlumi Ọlajengbesi, sọ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn yii ko nitumọ rara. O ni ohun to bi eeyan ninu ni, o ti ni loju pẹlu, ko si fẹsẹ mulẹ nibi kankan.

 Lati ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ti awọn DSS ti ya bo ile Igboho loru, ni Soka, n’Ibadan, ti wọn  paayan meji nibẹ, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ, ti wọn tun ko mejila ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ si ahamọ lawọn amofin gbogbo ti n sọ pe iwa to lodi sofin gbaa ni DSS hu.

Bi ko si jẹ pe awọn to n ja fun itusilẹ awọn ọmọ ẹyin ajijagbara naa ko sinmi ni, ahamọ ni gbogbo wọn ko ba ṣi wa.

 

Leave a Reply