DSS lawọn ko da eto igbanisiṣẹ awọn dokita to fẹẹ lọ si Saudi ru, ṣugbọn awọn eeyan ni irọ ni wọn pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latigba ti eto igbanisiṣẹ awọn dokita to fẹẹ lọọ ṣiṣẹ ni Saudi Arabia ti fori ṣanpọn l’Ọjọbọ, Tọsidee ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, lawọn eeyan ti n sọ ọ kiri pe ajọ DSS, iyẹn awọn ọtẹlẹmuyẹ ni wọn lọọ da awọn to n ṣeto igbanisiṣẹ naa lọwọ kọ. Koda, wọn ni wọn tun mu awọn akọroyin to n kọ bo ṣe n lọ silẹ paapaa.

Bo tilẹ jẹ pe DSS ti ta ko iṣẹlẹ yii, ti agbẹnusọ wọn, Peter Afunanya, ti ni ko ri bẹẹ, ati pe kawọn akọroyin maa ri okodoro ọrọ ki wọn too gbe e jade faye. Sibẹ, ọpọ awọn akọroyin tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe niṣe lawọn DSS de tijatija si gbọngan Ladi Kwali, l’Abuja, nibi tawọn dokita ilẹ wa to fẹẹ lọọ gbaṣẹ ni Saudi Arabia pọ si, ti wọn n fi iwe-ẹri wọn han awọn alaṣẹ eto naa, boya wọn yoo le gba wọn wọle sọhun-un, nigba ti ijọba Naijiria ko dahun si ẹbẹ wọn.

Niṣe ni wọn tu awọn dokita to n waṣẹ naa ka, ti wọn tun le awọn akọroyin to n ṣe akọsilẹ ohun ti wọn n ṣe naa silẹ. Nigba to tiẹ ya, wọn fọwọ ofin mu awọn akọroyin naa ni gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ọkan lara awọn akọroyin ti wọn mu ni wọn pe orukọ ẹ ni Marcus Fatunde. Ẹka iroyin to n ṣe itọpinpin lọkunrin naa n ba ṣiṣẹ, orukọ ileeṣẹ naa ni International Centre for Investigative Journalism. Wọn pada fi Fatunde silẹ lẹyin ti wọn ti tu awọn dokita ka tan.

Igbesẹ DSS yii ti mu kawọn ara Saudi to n ṣeto naa fi ti sibi kan na, nitori wọn ni ijọba Naijiria sọ pe nnkan itiju lo jẹ fawọn pe Saudi fẹẹ waa ko awọn dokita awọn lọ. Igbakeji Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, Adoje Arome, sọ fun iwe iroyin Punch pe awọn alaṣẹ eto naa fidi ẹ mulẹ foun pe awọn ti dawọ igbanisiṣẹ ọhun duro na, wọn ko si tilẹ wa sibẹ mọ.

Ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti eto igbanisiṣẹ yii bẹrẹ, niṣe lawọn dokita ilẹ yii ya bo ibẹ lati wa ọna ti wọn yoo maa gba ri ounjẹ jẹ. Awọn dokita naa sọ pe awọn kan ko tilẹ niṣẹ lọwọ ninu awọn rara, ijọba ko gba awọn siṣẹ, bẹẹ lawọn mi-in ninu wọn sọ pe owo tijọba n san fawọn ni ko daa, to kere ju, to si tabuku akọṣẹmọṣẹ dokita.

Wọn ni awọn si ti ba wọn sọrọ titi pe ki wọn gba ọrọ awọn ro, ijọba Naijiria ko dahun, niṣe ni wọn kọti ikun sohun to n jẹ awọn niya, eyi lo fa a tawọn fi fẹẹ ba Saudi to ṣetan lati gba awọn siṣẹ lọ.

Ninu fidio kan to jade lọjọ Iṣẹgun naa, awọn dokita yii fi ẹdun ọkan sọrọ, wọn ṣalaye bo ṣe jẹ pe iya buruku ni ijọba Buhari fi n jẹ awọn.

Ọmọbinrin dokita kan tilẹ wa nibẹ ti ọkan rẹ gbọgbẹ pupọ, iṣẹ loun naa wa lọ sibi tawọn eleto yii ti n yẹwe awọn dokita wo, afi bo ṣe ba olukọ rẹ to kọ ọ nileewe lọdun akọkọ pade, olukọ agba to jẹ ọga gidi ni nidii iṣẹ iṣegun oyinbo, baba naa wa to fun iṣẹ Saudi Arabia, nitori Naijiria ti fi oju rẹ ri mabo.

Dokita kekere naa fẹrẹ le maa sunkun bo ṣe n ṣalaye ohun to ri naa fawọn akọroyin, pe oun atọga oun jọ n to fun iṣẹ. O loun ko mọ pe nnkan ti bajẹ to yii ni Naijiria, oun sunkun fun ọjọ iwaju orilẹ-ede yii gidi.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di Ọjọbọ, ko si aaye lati ba awọn akọroyin sọrọ to bẹẹ mọ, nitori awọn DSS ti wọn ni wọn waa le wọn yii, afi awọn kọọkan ti wọn dọgbọn sọrọ ki wọn too maa mu awọn akọroyin naa, ti wọn jẹ kaye mọ pe ijọba ilẹ yii ti jẹ ki Saudi sọ eto naa rọ sibi kan na.

Leave a Reply