DSS lodi si beeli mẹrin ninu awọn ọmọlẹyin Igboho

Faith Adebọla

 Bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ, o ṣee ṣe ki wọn fi mẹjọ silẹ ninu awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho ti wọn ko wa sile-ẹjọ giga niluu Abuja l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii silẹ ti wọn ba ti yanju beeli wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeejila ni wọn ko wa sile-ẹjọ gẹgẹ bi adajọ ṣe paṣẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ti igbẹjọ naa waye gbẹyin nilẹ-ẹjọ giga kan niluu Abuja, sibẹ, o ṣee ṣe ko ma jẹ pe gbogbo awọn eeyan naa ni wọn yoo gba beeli wọn, afi ti adajọ ba ṣiju aanu wo wọn, to si da ẹbẹ ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ n beere nu.

Eyi ko sẹyin bi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ṣe ni awọn ko lodi si gbigba beeli mẹjọ ninu awọn eeyan naa, ṣugbọn awọn mẹrin kan wa ti awọn ko le fi silẹ ninu wọn nitori iwadii awọn fi han pe awọn eeyan naa lọwọ ninu kiko ohun ija oloro jọ ati iwa arufin. Wọn ni awọn ko le gba ki ile-ẹjọ gba beeli awọn eeyan naa.

Leave a Reply