Ọlawale Ajao, Ibadan
Dukia ti ko mọ ni owo kekere lo ṣegbe sinu ijamba ina to waye lọja Agbeni, n’Ibadan, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ohun tawọn kan n sọ saa ni pe o ṣee ṣe ko jẹ waya ina ilẹntiriiki to ti bo lo kọ lu ara wọn ninu ọkan ninu awọn ṣọọbu to wa ninu oja naa tina fi sọ. Bẹẹ lawọn kan n sọ pe boya ina amuku siga ti ẹnikan sọ silẹ nibi kan ninu ọja lo ṣee ṣe ko fa ijamba naa.
Lọrọ kan, ko sẹni to mọ ohun to ṣokunfa ijamba ọhun gan-an, awọn to kọkọ denu ọja naa laaarọ yii ni wọn debẹ ti wọn kan ṣadeede ri i tina n jo.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, loju-ẹsẹ lawọn to tete de ọja ti bẹrẹ si i rọmi lu ina ọhun lati pa a. Bi wọn ṣe n ṣeyi naa lawọn kan n pe ẹrọ ibanisọrọ awọn panapana.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Moshood Adewuyi sọ pe ṣọọbu mẹrin lọwọ ijanba ina ọhun ti ba ko too di pe wọn pe awọn, lọgan lawọn si yara lọ sibẹ ti awọn pana ọhun lai fasiko ṣofo.