Dukia to to miliọnu meje naira jona raurau nibi ijamba ina to ṣẹle niluu Iwo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Dukia to to miliọnu meje naira lo jona ninu ijamba ina to ṣẹlẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nileeṣẹ Rabsih Imec Nigeria Limited, to wa niluu Iwo, nipinlẹ Ọṣun.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle, sọ fun ALAROYE pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ni ijamba ina naa ṣẹlẹ.

Abala kan nileeṣẹ naa, nibi ti tanki meji to kun fun epo (oil) wa nijamba naa ti bẹrẹ, ati pe lọgan ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn kọja sibẹ.

O ni epo to wa ninu awọn tanki mejeeji naa ti wọn fẹẹ fi ṣiṣẹ nileeṣẹ naa to ẹgbẹrun lọna marundinlọgọta lita.

O fi kun ọrọ rẹ pe lojiji ni ina ṣẹ yọ ninu awọn tanki naa, ti gbogbo rẹ si bu gbamu, o si to wakati meji ki ileeṣẹ panapana too lanfaani lati pa ina naa.

Adekunle sọ siwaju pe awọn dukia to to miliọnu meje lo ba iṣẹlẹ ina naa lọ, nigba ti awọn ajọ panapana lanfaani lati daabo bo dukia to to biliọnu meji naira nileeṣẹ ọhun lọwọ iṣẹlẹ ina naa.

Leave a Reply