Ẹṣẹ ti emi Taye ba ṣẹ, Kẹhinde mi lo maa n jiya rẹ nigba ta a wa ni kekere- Ibeji Ọbasa

N ba b’ejirẹ n ba jo, ai b’ejirẹ dun mi, ẹdunjọbi ọba ọmọ. Nnkan iwuri lo maa n jẹ beeyan ba ri awọn ibeji bi wọn ṣe maa n rẹwa, paapaa nigba ti Ọlọrun ba wo wọn ti wọn dagba, ti wọn jọ n ṣe ohun gbogbo pọ, ibeji aa si maa wuuyan i bi.

 

Awọn ibeji kan ree ti wọn ri aanu gba, Taiwo ati Kẹhinde Ọbasa lati Igbore, l’Abẹokuta. Ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2021 yii ni wọn pe ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrun-un ( 87) laye, wọn jọ n ṣe ohun gbogbo pọ ni, koda, wọn jọ kọle ti wọn n gbe l’Abule-Ẹgba, l’Ekoo, ni. Eyi ni ohun ti wọn ṣalaye fun ADEFUNKẸ ADEBIYI, akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun.

 

KẸHINDE: Orukọ mi ni Francis Kẹhinde Ọbasa, ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 1934 ni wọn bi emi ati ekeji mi, Emmanuel Taiwo Ọbasa, ọmọ ilu Abẹokuta ni wa. Abule Igbokunla, n’Igbore, ni wọn ti bi wa.

 

A lọ sileewe alakọọbẹrẹ Anglican, l’Abẹokuta, iwe oni standard la ka (Standard 6)

Lẹyin ọdun diẹ, a wa s’Ekoo, nibi ta a ti ṣe pupọ aye wa. A gbe Yaba, Abule-Ijẹṣa, Surulere Muṣin, a gbe Pedro, a gbe Ṣomolu, ka too waa ralẹ si Abule-Ẹgba nibi, lọdun 1980, ta a jọ kọle

Mo bẹrẹ iṣẹ ni 1966, ni Josiah Park Nigeria Limited), awọn ni wọn n ṣe kọkọrọ Union, ọdun mẹtadinlọgbọn (27)ni mo fi ṣiṣẹ nibẹ. Ọdun 1966 ti mo debẹ yẹn naa ni mo fẹyawo, mo dẹ bimọ. Mo fẹyinti nibẹ ni 1985.

Nisinyii, iṣẹ ti mo n ṣe ni ka ba awọn eeyan ra ilẹ, ka ba wọn kọle.

TAIWO: Mama to bi wa ni Ọlaẹgbẹ Ọbasa, baba si ni Oke Ọbasa. Nigba ta a wa s’Ekoo, emi n ṣiṣẹ ni Imperial Chemical Industry, (ICI).

Mo ṣiṣẹ nibẹ fọdun mejidinlogun, nigba ti mo kuro nibẹ ni mo bẹrẹ si i ṣiṣẹ dẹrẹba, ki n too bẹrẹ si i ṣe sọpulai yẹepẹ. Mo n sọpulai pako naa bayii.

 

ILE TA A JỌ KỌ: Nigba ta a n gbe ni Bariga ati Muṣin, a n gbe lọtọọtọ ni, ṣugbọn adugbo kan naa la maa n wa. Ṣugbọn nigba ti a fẹẹ gba ilẹ ibi, a jọ dawo ra a ni, a jọ kọ ọ ni.

Ojule mẹwaa nile yii, a pin in ni marun-un marun-un. A kọ bọiskọta naa, ati ṣọọbu, a waa yọ yara kan silẹ ta a n fowo ẹ ṣe atunṣe awọn nnkan to ba bajẹ lara ile.

Ko si wahala kankan laarin wa, kaluku lo ni tẹnanti tiẹ, ifẹ dẹ ni gbogbo wa fi n gbe.

Koda, awọn iyawo wa paapaa ko faja laarin wa, bẹẹ naa lawọn ọmọ wa. Ki i ṣe pe a ki i ja rara, nitori ko si arẹmaja, ko dẹ si ajamarẹẹ. Ta a ba ja, a maa n pari ẹ laarin ara wa naa ni.

Emi Taiwo ṣegbeyawo lọdun 1965, emi ni mo kọkọ bimọ. Kẹhinde mi ṣe lọdun1966.

Awa kọ lakọbi awọn obi wa, a lawọn ẹgbọn niwaju, ṣugbọn nigba ti wọn ti bi wa ni wọn ti n tọju awa ibeji yatọ.

Awa mẹta pere la ṣẹku bayii ninu ọmọ meje ti awọn obi wa bi, Idowu wa ti ku ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin, ṣugbọn aunti wa agba ṣi wa, awọn jẹ ẹni ọdun mọkanlelaaadọrun-un( 91) bayii.

 

ẸNI TO MAA N BINU JU NINU WA:

Kẹhinde :Taye ni, ohun ta a ba ti kọ mọọyan, ko si ko ma ṣe e, oun lo maa n tete binu ju emi lọ. Ṣugbọn ibinu ẹ naa ki i pẹ, laarin iṣẹju marun-un, o ti binu ọhun tan, o pari niyẹn.

 

IRU ERE TA A FẸRAN:

Taiwo: Mo nifẹẹ si ere bọọlu afẹsẹgba, mo dẹ tun maa n lọ sile sinima lati wo fiimu.

Kẹhinde: Emi nifẹẹ si ki n jokoo ti awọn agbalagba, ki n maa kọgbọn lọdọ wọn, ka maa tayo ọlọpọn.

 

KO SẸNI TO BI IBEJI NINU WA: A o bi ibeji, Ko sẹni to bi ibeji ninu wa, awọn ọmọ wa paapaa ko ti i bi i.

 

WỌN MAA N ṢIWA MU SIRA WA NIGBA TA A WA NI KEKERE:

Taiwo: Nigba ti mo n ṣiṣẹ awakọ, ẹnikan to n ṣiṣẹ lọdọ awọn Kẹhinde wọ mọto mi, ko waa fẹẹ sanwo, o ro pe Kẹhinde lo tun n wa mọto ni. Mo sọ fun un pe ko sanwo mi fun mi ki n ma baa yẹyẹ o, emi o mọ ọn ri o.

Mo gbowo mi lọwọ ẹ, nigba to de ibiiṣẹ to tun ri Kẹhinde, o lọọ sọ fọgaa wọn pe iṣẹ meji lo n ṣe.

Kẹhinde waa sọ fun un pe ibeji loun, pe Taye oun lo ri, ki i ṣe oun rara. Ọga paapaa ko gba Kẹhinde gbọ, o loun maa da a duro lẹnu iṣẹ fungba diẹ bi ko ba lọọ mu ikeji ẹ naa wa. Afigba ti mo tẹle e debẹ ki wọn too gba pe ibeji ni loootọ, wọn ṣẹṣẹ waa fi i silẹ ko maa ba iṣẹ ẹ lọ.

 

LỌJỌ KEJI TI WỌN LỌỌ GBE WA JO LA BẸRẸ SI I GBONA

Awọn obi wa sọ fun wa pe lọjọ tawọn lọọ gbe wa jo nigba ta a wa ni kekere, ọjọ keji ẹ la bẹrẹ si i gbona, bẹẹ ko si nnkan kan to ṣe wa tẹlẹ. Wọn tun gbe wa lọọ jo nigba keji, a tun bẹrẹ si i gbona, bi wọn ṣe lọọ yẹ ẹ wo lọdọ awọn onifa niyẹn. Ibẹ ni wọn ti sọ fun wọn pe a o ki i ṣe ibeji onijo. Wọn ni Ọlọrun ti da wa daadaa, a o niidi ki wọn gbe wa jo, se ẹwa, ge ireke tabi se ekuru fun wa. Latigba naa ni wọn ko ti gbe wa jo mọ, a o si gbona mọ.

 

A MAA N GBEJA ARA WA BI WỌN BA N LU ENIKẸNI NINU WA

Taiwo: Ti mo ba ri i ti wọn n ba Kẹhinde mi ja, ma a kọkọ beere ohun to ṣẹlẹ. To ba jẹ Kẹhinde lo jẹbi, ma a pẹtu si i ninu, ma a dẹ mu un kuro nibẹ.

Ṣugbọn to ba jẹ oun lo jare, ti ẹnikan waa n lu u, wahala maa ṣẹlẹ o, a jọ maa fa a ni. To ba dẹ jẹ oun naa lo ba wọn nibi ti wọn ti n ba mi ja, o maa gbeja mi to ba ri i pe emi ni mo jare.

 

EMI TAIWO N ṢE FAAJI JU KẸHINDE LỌ:

Mo ṣi n mu sitaotu bẹ ẹ ṣe n wo mi yii, emi laiki faaji o. Ki n lọ sile ijo, kilọọbu, ka mu bia, ka ṣe faaji. Ana ode yii gan-an mo ṣi ṣe faaji.

Ki n jẹun tan, ki n rọra fi sitaotu kekere le e, ki ọkan mi balẹ.

 

ILE LA TI N JỌSIN BAYII, A KI I LỌ SI ṢỌỌṢI MỌ

Taiwo: Inu ijọ CMS, Anglican ni wọn bi wa si. Mi o kẹrẹ ninu imọ bibeli. Ti mo ba maa fi imọ mi ninu bibeli ti mo ni ṣe ni, ma a ti di General Overseer (Olori ijọ), ṣugbọn mi o ni i ṣe bẹẹ.

Lati ori Jẹnẹsiisi de Malaki, majemu laelae. Matiu de Ifihan, mi o kẹrẹ nibẹ.

Gbogbo awọn to da ṣọọṣi silẹ nisinyii, bii Adeboye, Kumuyi, Winner, ọmọ ni wọn jẹ fun wa lọjọ ori ati ninu imọ, ṣugbọn agbekalẹ wọn ti wọn n gbe kalẹ nisinyii ni ko jẹ ki emi ba wọn ṣe mọ, ti mi o lọ si ṣọọṣi mọ, nitori wọn ti sọ ṣọọṣi di ileeṣẹ.

Nigba ti awa n ṣiṣẹ ijọba, ọjọ Sannde la n lọ si ṣọọṣi, aago mẹwaa si mọkanla, ati kuro nibẹ, kaluku ti gba ile ẹ lọ, ko si iṣọ ọsan, ko si iṣọ oru. Ṣugbọn nisinyii, gbogbo awọn oniṣoọ ọsan ti de, ti wọn fi n gba awọn eeyan loju.

Ile wa la ti n ṣe isin bayii, ko sohun ti wọn fẹẹ sọ fun wa ni ṣọọṣi ta a o le kọ ara wa nile. A o kọja aaye wa ri, latigba ta a ti d’Ekoo yii, a o de teṣan ọlọpaa ri, bẹẹ naa dẹ lawọn ọmọ wa, a mọ ofin a dẹ n tẹle e.

 

OUNJẸ TA A FẸRAN JU

Kẹhinde: Amala funfun la jọ fẹran ju, a fẹran dudu naa. Ọbẹ gure ọlọbọrọ ti wọn fi ṣawa si la fẹran lati fi jẹ ẹ. A o fẹran raisi. Ẹba, amala, fufu awọn iyẹn lo daa.

 

A O KABAAMỌ OHUNKOHUN LỌJỌ OGBO WA

Taiwo: Ko sẹni to le tẹ aye lọrun, ṣugbọn ninu ohun daadaa teeyan n ṣe laye, a ti gba maaki to yẹ ka gba. A ti ṣe ohun to yẹ ka ṣe. A o kabaamọ kankan lori ba a ṣe gbe aye wa lọjọ ogbo ta a wa yii.

 

A O KI I LO IGO, OJU WA ṢI RIRAN DAADAA: A dupẹ f’Ọlọrun fun oore ọfẹ to fun wa. Titi dasiko yii, ta a ba fẹẹ ka bibeli, a n ka a lọọ geerege ni, a o ki i lo igo rara. Oju wa ṣi riran rekete.

 

IBEJI DAA, O MAA N JẸ KỌMỌ EEYAN TETE PỌ

Ibeji daa pupọ lati bi, wọn o ki i ku mọ nisinyii. Laye atijọ ti ko si itọju to, ti oju ko si ti i la daadaa, ni wọn n ku. Ibeji maa n jẹ kọmọ eeyan tete pọ ni. Iye ọdun teeyan dẹ maa fi tọ ọmọ kan naa lo maa fi tọ meji dagba. Ibeji daa gan-an, a daa pupọ, ko si wahala kankan lọrọ wa.

Leave a Reply