Ẹ fiṣẹ silẹ ti ẹ ko ba fẹẹ lọ si abule, SUBEB sọ fawọn tiṣa

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Ẹka to n ṣeto ẹkọ alakọọbẹrẹ nipinlẹ Ekiti, Ekiti State

Universal Basic Education Board(SUBEB), ti sọ pe olukọ ti ko ba f̣ẹẹ ṣiṣẹ

labule lanfaani lati kọwe fiṣẹ silẹ.

Ẹka naa koro oju si bi awọn tiṣa kan ko ṣe fẹẹ lọ si igberiko, eyi to mu ọpọlọpọ wọn jokoo si awọn ilu nla nipinlẹ naa, ti iya si n jẹ awọn to fẹẹ kawe lawọn abule kaakiri.

Alaga SUBEB l’Ekiti, Ọjọgbọn Fẹmi Akinwumi, lo sọrọ naa niluu Ikọgosi-Ekiti, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti, lasiko iṣide eto ọlọjọ marun-un kan ti wọn fi gbaradi fawọn oṣiṣẹ to n mojuto eto ẹkọ to ye kooro.

Akinwumi ni, ”A ko ni awọn olukọ lawọn ileto, wọn si pọ lawọn

ilu nla kaakiri. Bi nnkan ṣe ri yii n da wahala silẹ, iyẹn la ṣe fẹẹ bẹrẹ eto

pinpin awọn olukọ. Ti a ko ba wa nnkan ṣe lori eyi, a ko ni i tẹsiwaju.

”Awọn tiṣa ta a ni to fawọn ileewe wa, ṣugbọn ibeere to yẹ ka beere ni pe ṣe awọn tiṣa abule dẹṣẹ ni?

”Ilana tuntun ni pe ẹni ti ko ba gba ibi ta a gbe e si, ko kọwe fiṣẹ silẹ. Awọn kan gbagbọ pe awọn le lo ẹsẹ̀ lati yi nnkan pada, ṣugbọn ninu eto tuntun yii, awọn wọnyi gan-an la maa gbe.

Akọwe agba ẹka eto ẹkọ agbaye, Universal Basic Education Commission (UBEC), Ọmọwe Hamid Boboyi, ẹni ti Ọmọwe P. A. Oyedokun ṣoju fun, ṣapejuwe eto to waye lori ẹkọ to ye kooro ọhun bii ipilẹ eto ẹkọ, eyi to yẹ ki gbogbo eeyan ṣamulo.

O waa ni o yẹ ki iru ẹ maa waye loorekoore, kawọn olukọ le maa ṣe nnkan to tọ ni gbogbo igba fun igbelarugẹ eto ẹkọ.

Leave a Reply