Ẹ ni suuru diẹ fun ijọba Buhari, Lai Mohammed bẹ gbogbo ọmọ Naijiria

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Minisita feto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed, ti bẹ gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati ni suuru diẹ fun ijọba Muhammadu Buhari bo ti ṣe n tiraka lati mu ayipada rere to ṣeleri lọdun 2015 ba orileede yii.

Nibi ipade kan to waye niluu Ilọrin lopin ọsẹ to kọja ni Minisita ọhun ti sọrọ naa.

O rọ awọn ti ko ba ti i ri ipa tijọba to wa lori aleefa n ko tabi ti wọn ro pe ijọba ko ti i ṣe nnkan to, lati fun wọn lasiko diẹ si i.

Mohammed ni, “Ta a ba ti i ṣe to tabi kopa gidi ninu igbe aye gbogbo eeyan, a bẹ yin, ẹ ba wa fara da a fun igba diẹ.

“Lakọọkọ naa, owo ta a n pa wọle kere si ida ọgọta ohun tawọn ijọba to ṣaaju wa ri. Gbogbo wa la mọ pe ajalu Covid-19 de ba wa, bi a tun ṣe n kuro lori iyẹn ni rogbodiyan mi-in tun bẹ silẹ. A rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ni suuru fun ijọba”.

O nijọba gbe biliọnu marundinlọgọrin naira #75b kalẹ labẹ eto idokoowo fawọn ọdọ (National Youth Investment Fund). Eyi ni yoo fun wọn lanfaani lati ri owo gba fi ṣiṣẹ ati ṣowo.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Gomina Abdulrazaq Abdulrahman, Olori ile aṣofin Kwara, Ọnarebu Yakubu Danladi, Emir Ilọrin, awọn ori ade mi-in, aṣoju awọn ọdọ, awọn iyalọja atawọn mi-in bẹẹ lọ.

Leave a Reply