Ẹnikẹni to ba kọlu ọlọpaa yoo rija awa soja-Ogunṣugba

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olori awọn ọmoogun ilẹ yii nipinlẹ Ọyọ, Ọgagun T.A. Ogunṣugba, ti lu aago ikilọ fawọn tọọgi kaakiri ipinlẹ naa, o ni janduku to ba kọlu ọlọpaa yoo ba wọn lalejo lajule ọrun.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lo sọrọ yii lasiko abẹwo ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, lati ba wọn kẹdun iku awọn ọlọpaa ti awọn janduku pa lasiko iwọde ti wọn ṣe lọsẹ meji sẹyin, eyi ti ko ti i jẹ ki awọn ọlọpaa ti i maa ṣe ojuṣe wọn laarin ilu di ba a ṣe n kọroyin yii.

Ọgagun Ogunṣugba sọ fun awọn lọgaa lọgaa lẹnu iṣẹ ọlọpaa pe “Iṣẹ agbofinro ni lati daabo bo ilu. Ko si si ẹni ti yoo ba yin ṣiṣẹ naa bi ẹ ko ba ṣe e funra yin. Nitori naa, pẹlu agbara ta a gbe wọ yin yii, ẹ pada sẹnu iṣẹ yin lati tẹsiwaju ninu ojuṣe ti ofin ilẹ yii gbe fun yin ṣe.

“Awa ṣọja wa pẹlu yin. Ẹ oo ti maa ri i pe awọn ṣọja ti n tẹle awọn ọlọpaa kan kaakiri awọn adugbo kan bayii.  Ẹni ba doju ija kọ yin yoo rija awa paapaa, nitori abuku to ba kan ọlọpaa, o kan awa ṣọja naa pẹlu.”

Ṣaaju lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ,CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti fidi ẹ mulẹ pe ọlọpaa marun-un ati teṣan ọlọpaa marun-un ni wọn dana sun lasiko ikọlu naa nigba ti ọlọpaa mejila fara ṣeṣe yannayanna.

 

Nigba to n ki ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii ku atẹmọra awọn eeyan wọn to ku lasiko ikọlu awọn janduku oluwọde laipẹ yii, Gomina Makinde sọ pe mọlẹbi awọn ọlọpaa to doloogbe wọnyi wa lara awọn ti oun pinnu lati fun ninu ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira (N500m) ti oun ṣeleri fun atunṣe awọn nnkan to bajẹ lasiko ikọlu naa.

Bakan naa lo ṣeleri pe gbogbo nnkan maraarun ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii beere lọwọ ijọba oun pata loun yoo ṣe. Ninu wọn ni àtúnkọ́ awọn teṣan ọlọpaa ti wọn dana sun, ati ipese awọn ohun eelo iṣiṣẹ fawọn agbofinro.

Nigba to n sọrọ lori rogbodiyan to gbẹmi ọpọ eeyan ati dukia naa, Gomina Makinde sọ pe “Awọn to ṣewọde ki i ṣe janduku, nnkan to daa ni wọn ṣe, ọrọ ẹyin ọlọpaa naa si wa lara awọn nnkan ti wọn n ṣe iwọde le lori, wọn fẹ ki ijọba ṣagbekalẹ owo-oṣu to jọju fun yin. Awọn janduku to dara pọ mọ wọn lo sọ ọ di nnkan mi-in mọ wọn lọwọ”.

 

Igbakeji ọga agba ọlọpaa nilẹ yii, DIG Lẹyẹ Oyebade, pẹlu ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti wọn gba gomina lalejo waa dupẹ lọwọ ẹ fun bo ṣe fi ọjọ akọkọ ninu ọsẹ tuntun silẹ lati waa ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn.

Ṣugbọn inu awọn ọjẹ wẹwẹ ọlọpaa ko dun si Gomina Makinde fun ipa to ko lori rogbodiyan naa, wọn ni kaka ki gomina kilọ fun awọn oluwọde naa lati sinmi idaluru ati iwa ọdaju, niṣe lo tun fun wọn lowo lẹyin ti wọn dana sun odidi ọlọpaa meji laduugbo Iwo Road, ti wọn si jẹ wọn bii ẹran suya, ti gomina tun n ba awọn ọdaran naa dọwẹ̀ẹ́kẹ̀.

Leave a Reply