Afaimọ ki ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta kan, Tairu Raheem, ma faṣọ penpe roko ọba lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o fun ọmọleewe ti wọn porukọ ẹ ni Simiat Oseni loyun, o tun gbiyanju lati ṣẹyun fọmọ ọlọmọ niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ.
ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe iṣẹ awakọ ero ni Ọgbẹni Raheem n ṣe, nigba ti Simiat n kẹkọọ lọwọ nileewe girima Ọtun Community High School, niluu Ṣaki, ipele kilaasi JS tuu (Junior Secondary 2) lo wa nigba tọrọ yii ṣẹlẹ.
Ọmọ ti afurasi ọdaran yii ki mọlẹ ti jẹwọ pe niṣe ni ọkunrin yii maa n ran oun niṣẹ oriṣiiriṣii nigba toun ba ti dari de lati ileewe, tori ile ti wọn n gbe ko jinna sira. Ori iṣẹ riran yii lo ti bẹrẹ, o si maa n fun oun ni ṣenji to ba ṣẹku lai mọ pe o fẹẹ wọle soun lara ni.
Ọmọbinrin naa ṣalaye pe inu kilaasi akọku kan to wa lọgba ileewe awọn ni Tairu ti kọkọ ṣe ‘kinni’ foun fun igba akọkọ, ẹyin eyi lo tan oun wọn inu yara rẹ, to si ba oun laṣepọ.
O ni aimọye igba lo ti ba oun sun lẹyin ninu yara rẹ, o maa ni koun waa ba oun ra nnkan, toun ba si ti lọ toun ti bọ, ibasun lo fi n dupẹ lọwọ oun. Ko pẹ rara ti ọlẹ sọ ninu ọmọbinrin yii.
Mọlẹbi ọmọleewe naa, Alaaja Rukayat Fatai, ṣalaye fakọroyin wa pe akiyesi bi Simiat ṣe n ṣe lo mu kawọn fura pe boya lọmọ naa o ti fẹraku, lawọn ba tẹ ẹ ninu daadaa pe ko jẹwọ ohun to ṣẹlẹ.
Wọn lọmọ naa la a mọlẹ pe Tairu lo foun loyun, oun naa si jẹwọ pe loootọ ni, oun loun fun ọmọde kekere naa loyun.
Wọn lọkunrin naa bẹrẹ si i bẹbẹ pe ki wọn foriji oun, ki wọn ba oun ṣe ọrọ naa lokuu oru, o si ko ẹgbẹrun mẹwaa naira (#10,000) kalẹ pe ki ọmọ naa lọọ ṣẹyun ẹsin naa danu. Ṣugbọn oju ẹsẹ kọ lo kowo kalẹ o, oyun ti di oṣu mẹfa ko too ri owo ṣiṣẹyun.
Aipẹ yii ni wọn lọmọbinrin naa fi oyun ọhun bi obinrin, ṣugbọn latigba ti ọmọbinrin naa ti bimọ, wọn ni Tairu kọ, ko yọju sibẹ, debii pe o maa ki wọn tabi ṣaajo iya ọmọ rẹ.
Eyi n lọ lọwọ ni aisan da Simiat gunlẹ, aisan naa si pọ gidi, koda o diẹ lo ku ko la iku lọ. Asiko ti aisan naa bureke ni wọn gbe ọmọ Simiat fun awọn mọlẹbi baba rẹ.
Nigba ti ara Simiat ya, o beere fun ọmọ rẹ, ṣugbọn awọn mọlẹbi ọkọ naa ko fẹẹ da ọmọ ọhun pada, eyi lo si mu ki idile mejeeji sọko ọrọ lu ara wọn, ni awọn eeyan Simiat ba lọọ fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti ni teṣan wọn.
Ṣa, awọn ọlọpaa ti ni kawọn mọlẹbi mejeeji, ati baba ati iya ikoko, ati ikoko naa funra ẹ foju kan wọn ni teṣan lati sọrọ naa, ati pe dandan ni ki afurasi ọdaran yii yọju.