Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn Fulani bii mejidinlogun ni ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti da pada si ipinlẹ onikaluku wọn lẹyin tọwọ tẹ wọn nibi ti wọn ti n rin kiri niluu Akurẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Alakooso ẹsọ alaabo ọhun, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, pe agbegbe gareeji Ileṣa to wa niluu Akurẹ, lawọn ti kọkọ kofiri awọn ara Oke-Ọya naa ninu ọkọ ajagbe to ko wọn de.
O ni lati ibẹ lawọn ti n le wọn titi de agbegbe Arakalẹ, nibi ti wọn ti ba ọkọ wọn.
Olori ẹsọ Amọtẹkun ọhun ni ko si eyi tawọn ajoji ọhun ri dahun ninu gbogbo ibeere tawọn n beere lọwọ wọn, o ni kantankantan bii ọmọ ku lọwọ aditi ni wọn n sọ nigba tawọn n beere lọwọ wọn ibi tí wọn ti n bọ ati ohun ti wọn waa ṣe.
O ni igba miiran, wọn le ni Sokoto lawọn ti wa, lẹyin iṣẹju diẹ, wọn aa tun ni ipinlẹ Jigawa ni.
O ni ọrọ wọn ti ko jọ ara wọn lawọn ṣe ko wọn lọ sinu ọgba ileeṣẹ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, nibi tawọn ti kọkọ fun wọn lounjẹ ati mimu ki ọkan wọn le balẹ.
Lẹyin naa lo ni oun ransẹ si olori awọn Hausa nipinlẹ Ondo, toun si fa awọn eeyan ọhun le e lọwọ lati ṣeto bi yoo ṣe da wọn pada si ipinlẹ koowa wọn.
Oloye Adelẹyẹ ni awọn ri i gbọ lati ẹnu awọn Fulani tọwọ tẹ ọhun pe awọn ẹgbẹ wọn bii ọgbọn ni wọn ti kọkọ gunlẹ sipinlẹ Ondo ki awọn too de.
O ni ohun to jẹ awọn logun bayii ni bi ọwọ ṣe fẹẹ tẹ gbogbo awọn ti wọn sọ naa nitori pe o ṣee ṣe ki ipinlẹ Ondo wa ninu ewu ti awọn ko ba tete ri wọn mu.