Ẹ ṣofin kawọn lanlọọdu yee gbowo ile lọdọọdun, oṣooṣu ti daa – Faṣọla

Faith Adebọla, Eko

Minisita feto iṣẹ ode ati ọrọ ile gbigbe nilẹ wa, Amofin Babatunde Raji Faṣọla, ti gba gbogbo awọn gomina ipinlẹ kaakiri orileede yii lamọran pataki, o ni ki kaluku wọn lọọ ṣofin lawọn ipinlẹ wọn, oṣooṣu lo daa kawọn lanlọọdu maa gbowo ile, eyi lo si le din inira tawọn ayalegbe n koju ku.

Faṣọla sọrọ yii nibi ipade apero apapọ lori ọrọ ilẹ, ile gbigbe ati isọgbẹ-digboro (National Council on Lands, Housing and Urban Development) eyi to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Ọkunrin to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko naa sọ pe: “O le ma ṣee ṣe lati sọ gbogbo eeyan di onile lori, gbogbo wa si kọ lo maa di lanlọọdu, ṣugbọn a le mu adinku ba iye eeyan to n laalaṣi lori ile gbigbe, atawọn eeyan ti ko nile lori rara, titi kan awọn ti ipaya maa n mu nigba ti asiko ati san owo ile wọn ba to.

O da mi loju daadaa pe orileede wa maa dara lati gbe ti a ba le ṣofin lati wọgi le asansilẹ owo ile ọdun mẹta, ọdun meji, tabi ọdun kan lẹẹkan naa, inira nla lo jẹ fawọn ti wọn o fi bẹẹ ri ṣe, o si yẹ ka fagi le e. Ẹ ṣofin lati sọ gbigba ati sisan owo ile di oṣooṣu, ipari oṣu si ni kawọn eeyan maa san, ki i ṣe asansilẹ.

Loootọ, ibi ti a n lọ ṣi jinna, a le ma de ibẹ lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn ọrọ yẹ fun afiyesi lapa ibi yii, ti awọn aṣofin ipinlẹ ati tawọn kansu ba ṣofin lori ẹ, o maa daa fun awọn eeyan wa gidi.

Ijọba apapọ o ni agbara lati ṣe iru ofin bẹẹ, awọn aṣofin ipinlẹ lọrọ naa ja le lejika, ẹ ma kọyin si inira awọn araalu, ẹ jẹ ka maye dẹrun fun wọn. Kawọn gomina atawọn kọmiṣanna tọrọ kan si fun ọrọ yii lafiyesi akanṣe, eyi lo le din iṣoro airilegbe ati inira awọn eeyan wa ku jọjọ.
Bẹẹ ni Faṣọla sọ.

Leave a Reply