Nigba ti Safu ti sọ pe ki n fọkan si i, n oo ra ile Oṣodi yii, emi naa ti fọkan si i. Mo bẹrẹ si i fọkan ṣẹ gbogbo owo ti mo ti tọju si awọn banki yii, mo si mọ pe diẹ lo ku ki owo naa pe. Banki meji naa ni mo n tọju owo si, mo ti pe wọn, mo ni ki awọn maneja wọn waa ri mi, ọjọ kan yẹn naa ni o, laarin wakati kan ni takọkọ ti de, iyẹn si lọ ko ti i le pe wakati meji ti ekeji naa fi waa yọju si mi, o ni awọn n ṣe mitinni. Mo saa sọ ohun ti mo fẹ fun wọn. Awọn banki mejeeji ni kekere niyẹn, pe awọn maa ra a, awọn si maa sanwo ẹ, ma a waa ṣeto bii ẹni to n san owo rẹnti loṣooṣu tabi lọdọọdun ti gbogbo owo yẹn fi maa jẹ sisan.
Ṣugbọn awọn mejeeji ni wọn sọ pe ọrọ naa maa de hẹdikọta awọn l’Ekoo lọhun-un, mo si ni ko buru, bẹẹ ni mo jẹ kawọn mejeeji mọ pe banki meji ni mo n ba sọrọ o, ẹni to ba yara ju ninu wọn ni o. Gbogbo bo ṣe n lọ ni mo sọ fun Safu, o kuku tiẹ wa nibẹ nigba ti mo n ba maneja banki keji yẹn sọrọ. Igba ti a ṣetan ni mo ni ki oun duro si ṣọọbu, mo ni iko jẹ ki n lọọ ri baba lọọya ti mo maa n lo fun awọn nnkan nla bayii. Agbalagba ni wọn, ni Ilupeju ni wọn wa, lara awọn ti wọn maa n ṣe keesi nla nla pẹlu ijọba yẹn ni wọn.
Mi o fẹ lọọya kuẹkuẹ kan si iru eleyii, nitori nigba naa ni yoo di pe wọn yoo gbabọde fun oluwa-ẹ. Oju Safu naa ni mo ṣe n pe wọn, nigba ti wọn si ti ni awọn maa maa duro de mi ni mo ṣe gbera ti mo n lọ. Oun duro si ṣọọbu. Ẹ ẹ gbọdọ ri i bi inu ẹ ṣe n dun, ẹ oo ro pe mo ti ra ile naa ni. Nigba ti mo ri lọọya ti mo ṣalaye fun wọn, baba ni nnkan to dara ni, awọn maa ran-an-ya lọọ ba awọn onile, wọn gbọdọ ko iwe to wa lọwọ wọn wa ki wọn lọọ yẹ ẹ wo ni tan-un pilani, ko ma jẹ wọn ti fi yawo tabi pe gbese kan wa lori ẹ.
Nibẹ ni kinni kan ti sọ si mi lọkan, mo ni n ko ni i fẹ ki wọn darukọ mi si i, ki wọn ṣaa ti sọ pe awọn fẹẹ ra a fun onibaara awọn kan ni, lọjọ ti wọn ba fẹẹ gbowo paapaa, ọọfiisi wọn ni wọn maa wa, nibẹ la ti maa yanju ẹ. N ko fẹ nnkan ti n ko ni i ti i bẹrẹ ti ariwo ti maa gba gbogbo Oṣodi pe Iya Biọla tun de o. Baba yẹn ni o daa bi mo ṣe ronu, pe bẹẹ naa la maa ṣe. Nigba ti mo si pada de si ṣọọbu naa, ohun ti mo sọ fun Safu niyẹn. Ẹni meji ni n ko le ṣe ki n ma sọ fun, Sẹki ati Alaaji ni. Sẹki o ni i jẹ sọ fẹnikan, ṣugbọn Alaaji, afi ki n bẹ ẹ daadaa, o le bẹre si i fọnnu kiri pe iyawo oun ti ra gbogbo ile Oṣodi.
Bi mo ṣe sọ fun Safu lo ni ki n jẹ ka yaa tete sọ fun ẹni to pe mi si i o, nitori ọdọ ẹ gan-an lọrọ ti le kọkọ daru wa. Ni mo ba pada lọọ ba Aunti Jẹmila, ni mo ba sọ fun un. O ni ki lo n ba mi lẹru, ko si nnkan kan tẹnikan le fi mi ṣe. Ẹni ba dẹ fẹẹ ṣe were, were ti oun gan-an maa ṣe fun un maa ju nnkan ti tọhun ro lọ. Mo ṣaa bẹ ẹ pe n ko ti i fẹ ki orukọ mi jade nidii ẹ, pe ko jẹ ka yanju ẹ na. Mo ni lọọya lo maa waa ba a, awọn ni wọn jọ maa sọrọ, oun lo si maa mu un mọ awọn mọlẹbi to ba ku. Inu ẹ dun gan-an nigba ti mo sọ fun un pe mo fẹẹ gbiyaju ẹ wo.
O ni ko si iyanju kankan nibẹ, oun lọkan oun fẹ ki n ra a, emi ni mo si maa ra a. Loun naa n sọrọ bii Safu. Ile Sẹki ni mo gba lọ ki n too dele, mi o ba a, o ti lọ si ọsibitu, wọn ni wọn ti fẹẹ diṣaaji Iya Tọmiwa, ọsẹ yii naa ni wọn maa ni ko maa pada bọ nile, a jọ maa lọọ gbe e ni lagbara Ọlọrun. Ṣugbọn mo ranṣẹ silẹ fun un pe ko foju kan mi bo ba ti de. Alaaji wa lọdọ Aunti Sikira nigba ti mo de, sibẹ, mo yọju si wọn, mo si ki i daadaa. Ni mo ba sọ fun pe mo fẹẹ ri wọn ti wọn ba ti ṣetan. Afi bo ṣe dide yau, lo ni ki n jẹ ka lọọ sọ ọ.
Boya o ti fẹẹ sa kuro lọdọ Aunti Sikira tẹlẹ ni o, boya ifẹ to si ni si mi lo pọ to bẹẹ loootọ, emi o mọ o, o ṣaa dide, o tẹle mi, n la ba lọ si palọ ẹ. Ni mo ba kunlẹ, mo ni bayii kaṣa, bayii kawodi, mo ṣalaye bi wọn ti pe mi sile ti ṣọọbu wa wa, ati bi mo ṣe fẹẹ gbiyanju lati ra a, nitori ibẹ jẹ mi lọwọ, ti wọn ba si ta a fẹlomi-in, o le le wa jade to ba dọwọ ẹ, mo ni Safu gan-an lo fun mi nimọran bẹẹ. Alaaji! Ọkọ mi! Oninuure ẹda ni, afẹnifẹrere gbaa ni. Ko si ohun to o fẹẹ ṣe ti yoo tori ẹ binu, inu ẹ yoo dun ṣaa ni.
Ani niṣe lo dide to kọkọ fori balẹ lẹẹmẹta, to ni awọn baba oun ṣeun ṣeun, ti wọn ko jẹ ki toun gbe s’Ekoo. Lẹyin iyẹn naa lo waa ni ṣe ẹnu lo yẹ ki emi fi sọ iru ọro bẹẹ foun, pe ṣebi o yẹ ki n mu ṣinaapu dani. Mo ni nigba ti n ko ti i ra a, ti n ko ti i sanwo, ti n ko tiẹ ti i mọ bi owo naa yoo pe tabi ko ni i pe. Lo ba n rẹrin-in, o ni owo naa yoo pe, yoo tun le, nigba ti mo ba ra a tan, oun ko ni i gba sinaapu, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meji loun yoo gba bii owo idawọọ idunnu oun, pe bi oun si ṣe n wo mi yii, ki n kọkọ tọwọ bọ inu baagi mi ki n ko ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn foun, pe owo awọn ọmọ onilẹ niyẹn.
Ni mo ba gbẹrin, mo ni, ‘Haa, ṣe ọkọ mi ti tun di ọmọ onilẹ l’Oṣodi ni!’ Ṣugbọn mo ṣe bo ṣe wi o, mo ka ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn le e lọwọ bayii. Lo ba gba a, lo ni, ‘Ẹni kan ki i mọ bomi ṣe n wọ inu agbọn, ko sẹni to maa mọ aṣirii ibi ti mo ti maa ri owo ile naa san!’ Ni mo ma ṣami, inu mi si dun gan-an pe ọkọ mi fọwọ si i, nitori bo jẹ ọkunrin mi-in ni, agidi ni yoo ko bori, tabi ko bẹrẹ si i binu. O le ni n ko sọ foun ki n too lọọ ri ẹni to waa pe mi si i, ati awọn ọrọ ilara mi-in bẹẹ. Ṣugbọn iyẹn ki i ṣe ti ọkọ mi, ko o ma ti i dawọ le nnkan rere kan ni, bo o ba boju wẹyin bayii, oun lo o ri lẹyin ẹ!
Mo bẹ ẹ ko ma sọ fẹnikan ṣaa o, o ni oun kẹ, to jẹ gbogbo alangba lo dakun delẹ ti a ko mọ eyi ti inu n run ninu wọn. O ni o digba ti mo ba ra ile naa ki awọn araadugbo too gba pe oun lọkọ madaamu onile-tuntun l’Osọdi. Nibi ti a ti n sọrọ yẹn ni Sẹki ti de, lo n pariwo ‘Iya mi! Iya mi!’ lati ita. Ni mo ba sare jade si i, ni mo fa a lọwọ, lo ba di oke, bẹẹ lo n sọ fun mi pe ‘Jiisi wa! Iya ẹ, Jiisi wa!’ Mo mọ pe ko si ‘jiisi’ meji ju ọrọ Iya Tomiwa lọ. Aṣe ko tiẹ ti i dele, ko mọ pe mo ti lọ sile oun, ọkan kan riran lo jẹ ko ya lọdọ wa. Ni mo ba ṣalaye ọrọ ile naa fun un o.
Afi wuya to fo soke, o ni oun lalaa nijẹta, oun ri i ti ṣọọbu wa yẹn di nla, to waa tuntun, ti wọn wa n sọ pe ṣọọbu tuntun ti iya oun ṣẹṣẹ kọ ni. Mo ni ko ti i sowo ṣaa o, o ni ki n tutọ ẹ danu, o ti ṣee ṣe. Loun naa ba tun n jọ. A jẹ pe loootọ loootọ, mo maa ra ile Oṣodi yii o.