Ẹ ba mi dupẹ, Sẹkinatu Abẹjẹ, ọmọ mi ti bimọ o

Ẹ wo o, nnkan ti waa bajẹ patapata. Ọrọ aye yii, ti mo ba ni ki n maa ro o, oluwa ẹ ko ni i ṣe nnkan meji mọ o. Ṣe ẹ mọ pe nigba kan, ilu oyinbo ni opin irin-ajo fun awọn ọmọ wa. Ti wọn ba ti lọ sọhun-un, idunnu to maa n ba wa ki i ṣe kekere, ṣugbọn awọn ohun ti mo n ri lẹnu ọjọ mẹta yii fi han pe ọrọ yii ko ma ri bii ti atijọ mọ o. Ṣe ẹ mọ pe mo sọrọ ti Biọla mi fun yin, bi mo ba bẹere pe bawo ni nnkan ṣe wa n lọ si, aa ni awọn n surọgu ni. Oyinbo kan ṣoṣo to da si i lẹnu ju niyẹn: awọn n surọgu. Sẹki lo ti jẹ ki n mọ tipẹ pe awọn n tiraka ni wọn n pe ni surọgu.

Bi ki i baa ṣe pe ọrọ naa de oju ẹ, Biọla o ni i fi owo ẹ ranṣẹ sẹni kan, bẹẹ ki i ṣe ọmọ bẹẹ, ọmọ to lawọ ni. Emi naa si foju ara mi ri i nigba ti a de ọdọ wọn lọjọsi naa, ko si nnkan kan, surọgu yii ni ṣaa, keeyan ṣiṣẹ lati aarọ sulẹ ko tun ti bẹ jade laago mẹta oru nijọ mi-in, surọgu wo lo tun gbọdọ ju iru iyẹn lọ. Amọ nigba ti eeyan ba tun ro ohun to n ṣẹlẹ nile nibi naa, ti eeyan foju ri bi nnkan ṣe n lọ si, aanu awọn ọmọ naa yoo ṣe oluwa ẹ, ti wọn tun wa nile, ti wọn o ri nnkan ṣe. Awọn ẹgbẹ Akin ti wọn n rin kiri Oṣodi ko niye, wọn si ti jọ jade ni yunifasiti lati bii ọdun gbọgbọrọ sẹyin. N ni gbogbo ọrọ naa tiẹ ṣe su mi.

Ọrọ ọkunrin kan to wa lati ilu oyinbo ni mo ranti ti mo fi n sọ gbogbo eleyii o. E wo o, ẹ ṣaa maa ba mi dupẹ, adura yin lori mi n ṣiṣẹ o. Gbogbo bẹ ẹ ti n gbadura fun mi, mo mọ ọn o, mo si n ri i, ẹ ma dakẹ adura fun mi o. Diẹ lo ma ku ki wọn paayan si mi lọrun lọsẹ to kọja yii. Ẹyin naa ṣe ‘haa!’ Wọn fẹẹ paayan si mi lọrun o, Ọlọrun lo yọ mi o. Ọrọ ile ta a ra l’Oṣodi yii ni o. Wọn ni maanu kan wa ninu awọn ti wọn nile, pe iya ẹ ni wọn fun ni yara kan ninu ile wọn yii, ṣugbọn iya ti ku, oun si ni akọbi iya ẹ, oun ni yara kan naa tọ si. Ṣugbọn ilu oyinbo lo wa.

Bẹẹ ni, Tọki abi Yuroopu ni wọn ṣaa sọ pe o n gbe, emi o mọbẹ. Ohun ti Aunti Jẹmila pada waa sọ femi ni pe ọmọ ẹgbọn oun kan naa wa to ni yara kan ninu ile wọn yii naa, oun wa l’Ekoo nibi, olowo to ti ri ṣe tẹlẹ ki nnkan too daru bayii ni. Amọ awọn eeyan ko mọ pe nnkan ko lọ deede fun un mọ. Nitori bẹẹ, nigba ti wọn n pin owo yii, miliọnu marun-un lo kan oun, miliọnu marun-un naa lo kan ara ilu oyinbo, ni wọn ba ko miliọnu marun-un ara ilu oyinbo fun Alaaij Baṣiru (Bẹẹ ni, o ti lọ si Mẹka! Eyin goolu lo wa lẹnu ẹ paapaa).

Wọn o tiẹ deede kowo naa fun un o, eyi to wa niluu oyinbo, ṣe Luku ni wọn n pe e, wọn loun lo ni ki wọn ba oun ko owo naa fun ẹgbọn oun, awọn mọ ọwọ ara awọn. Ni wọn ba kowo fun Abeṣujobi o, Baṣiru naa lo n jẹ bẹẹ! Ko tiẹ sẹni to tun wadii owo laarin wọn, afi bi gbogbo famili ṣe gbọ pe wọn ti gun Abẹsujobi lọbẹ pa o. N lọrọ ba di girigiri, ko ti i si ẹni to mọ ibi ti wọn ti gun un lọbẹ pa, wọn tiẹ ro pe awọn ti wọn n ṣe iwọde SARS lo ko si laarin ni. Ere ni wọn sa de ọsibitu, ni wọn ba ri i pe loootọ ni wọn fi ọbẹ tu ifun ẹ jade.

Awọn famili ti n pariwo pe ki lo de ti wọn ko ti fi ọrọ to ọlọpaa leti, igba naa ni wọn too gbọ pe Luku lo wale lati ilu oyinbo, o si ti ni oun yoo pa Baṣiru, afi to ba sanwo oun foun. Aṣe Abeṣujobi ko ko owo Luku silẹ, wọn lo ni oun sare lo o fun bisinẹẹsi kan ni. Ohun ti ko jẹ ko le pe ọlọpaa niyẹn. Inu bi awọn famili naa, ni wọn ba n kuro nikọọkan, afi awọn ti aanu ẹ n ṣe ninu wọn ati awọn ti oun naa ti ran lọwọ ri. Ko waa ku ibi ti wọn yoo ti rowo fun Luku, Luku si ni wọn lo n sọ kiri pe bi Baṣiru ba fi le jade nibẹ yẹn, oun yoo tun da a pada sọhun-un ni, afi to ba ko owo oun bọ lati ọsibitu.

Eyi to tiẹ wa n dun mi ni ariwo temi ti wọn n pa lori ọrọ yii. Wọn ni ohun ti wọn n sọ ni pe ile ti Iya Biọla ra lo sọ Baṣiru dero ọsibitu o, owo ti Iya Biọla na fun wọn lo daja silẹ o. Ẹ gbọ, ṣe iru iyẹn daa. Abi iru iwa asọnilẹnu wo niyi. Nigba ti ki i ṣe pe mo jẹ wọn lowo, mo ti ra ile, mo si ti sanwo, ti wọn ba waa ṣe jamba funra wọn, kin ni wọn n darukọ temi si. Wọn yoo kan maa sọ oluwa ẹ lẹnu, ile ti mo ti ra ti mo ti gbagbe, ki waa ni temi. Eyi to ti ilu oyinbo wa to n gun wọn lọbẹ, ati eyi to gbowo ti ko ko o silẹ, ewo ni mo mọ ninu wọn.

Nibi ti Safu ti n bẹ mi pe ki n ma jẹ ki ẹnikan ba mi lọkan jẹ ni nnkan ayọ ti ṣẹlẹ nile wa. Sẹki lo bimọ o. Ẹ ba mi jo, ẹ ba mi yọ o, Abẹjẹ Sẹkinatu, Ọmọtori-ọla-waye idi ilẹkẹ, Ara Ake ọmọ majo meji, ọmọ ajogberu, ma jo gbẹkọ, ẹru ni i sin ni, ẹkọ ki i sin-in-yan. Ọmọ mi ti bimọ o. Bi mo ṣe n jo ti mo n ki oriki ẹ niyẹn nigba ti wọn waa ju iroyin ayọ naa lu mi ni ṣọọbu, ni Safu ati Abbey olori konko yẹn ba n fi mi rẹrin-in, wọn ni awọn ko mọ pe emi mọ ọn jo bẹẹ yẹn. Kia ni mo yaa gbe baagi mi, ọṣibitu ya, ki n lọọ ki iya atọmọ.

Bi mo ṣe n jo lẹẹkan ni ṣọọbu ni mo ti n darukọ ti mo maa sọ ọ, mo ni ,’ Haa, Oluwamayọwa niyi o!’ Ohun to si jẹ ki n sọ bẹẹ ni ironu to ba mi lori ohun ti awọn ti mo ra ilẹ lọwọ ẹ ṣe, bi wọn ti n ba mi lorukọ jẹ kiri lori ohun ti ko kan mi. Ṣugbọn bi mo ti ṣe gbọ iroyin ayọ naa, mi o mọgba ti mo pariwo pe Oluwamayọwa niyi, o si da mi loju po orukọ ti mo maa sọ ọ naa niyẹn, ki n le fi maa ranti ọrọ ile yẹn. Afi ti Abbey, ọmọ ẹlẹnuugbọrọ yẹn, o ni, ‘Iya mi de pẹlu asọdun! Oluwamayọwa kin ni! Ki i ṣẹ Koromayọwa ni! Abi ẹ fẹẹ sọ pe ẹẹ mọ pe asiko Koro ni wọn ṣe e!” Ni Safu ba pariwo, “Haa, Abiọdun!”

Leave a Reply