Faith Adebọla
“O digba ti a ba da a silẹ ti a tun un to, ti a ba ṣe ifọsiwẹwẹ awọn ipinlẹ ati ijọba ibilẹ yẹlẹyẹlẹ ta a ko jọ yii, ti a si yọ ipinlẹ mejila, tabi ẹkun mẹfa jade, igba naa la toO le maa sọrọ ilọsiwaju ati idagbasoke to jọju lorileede wa, igba naa si ni Naijiria le goke agba.”
Ọrọ yii lo jade lẹnu alaga tẹlẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, Ọjọgbọn Attahiru Jega niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nigba to n sọrọ lori bi itẹsiwaju ṣe le ba orileede Naijiria loju ipenija ta a n koju rẹ lasiko yii.
Ọjọgbọn naa ni ariwo tawọn eeyan n pa lọtun-un losi kaakiri orileede yii pe awọn fẹ ki atunto waye ko ṣẹyin aidọgba ati irẹjẹ to foju han ninu eto oṣelu ati iṣakoso Naijiria, ati pe ijọba buruku tawọn onṣejọba ti ko kunju oṣuwọn n dari, iṣejọba ti ko peye, iwa imọtara-ẹni-nikan awọn oloṣelu, gbogbo ẹ lo sọ orileede yii di ẹdun arinlẹ to wa yii.
Nibi ijiroro ọhun to da lori wiwa ọna abayọ fun Naijiria, Ọjọgbọn Jega sọ pe “ṣaaju ọdun 1966, ẹkun mẹfa pere ni Naijiria pin si, lawọn ọdun 1976 si 1977 si ree, ipinlẹ mejila pere la ni, afi ka pada si ọkan ninu eto mejeeji yii to ba jẹ loootọ la fẹ ki ilọsiwaju ba orileede yii.
Bawọn kan ṣe n sọ pe ki wọn tubọ pin orileede yii si ipinlẹ mejilelogoji (42) si i ki i ṣe ero to daa rara, ko tiẹ le ṣee ṣe ni, ẹnu dun i ro’fọ ọrọ lasan ni. Owo ati aayan oṣelu ti iru igbesẹ bẹẹ maa na wa maa pọ ju anfaani to maa mu wa lọ. Bawọn ipinlẹ ba ṣe n pọ si i to, bẹẹ ni eto ọrọ-aje ati ti iṣẹlu wọn maa maa mu ipenija ọtun wa to, bẹẹ la oo si maa ni awọn iha to pọ ju ati iha to kere ju si i, ti kaluku yoo si maa ja fun ẹtọ rẹ.
O ni ipade tawọn n ṣe lasiko yii jẹ lati gbe awọn adari tuntun dide kaakiri awọn ipele iṣejọba to wa, yatọ sawọn ta a ti mọ tẹlẹ, ki wọn le wa ojuutu siṣoro to n mu Naijiria lomi yii.