Ẹ ẹ ri i pe iṣẹ Ọlọrun yii ko ṣee tu wo, Ọba alaṣepe ni

Gbogbo ọna ni ọkan mi fi balẹ, nitori awọn iṣẹ ti kaluku n jẹ fun mi yii, awọn iṣẹ ti n ko ro tẹlẹ ni. Ṣugbọn ko digba teeyan ba sọ fun mi, mo mọ pe adura ti gba, pe Ọlọrun ti pari iṣẹ naa, nitori bi gbogbo ẹ ṣe n lọ yii, o n ya mi lẹnu ni o. O fẹrẹ jẹ ko si ibi kankan ti mo na ọwọ si, tabi ti wọn ti gbọ ọrọ yii ti atako wa nibẹ, kaluku ṣaa n sọ pe ohun ti mo fẹẹ ṣe yii, ire lo maa ja si ni. Ṣe ti Safu ni mo fẹẹ wi ni, abi ti Sẹki, abi ti baba wa funra ẹ! Akin lo tun de to ni oun lalaa yii. Ohun ti mo si sọ fun un naa niyẹn, mo ni a wa lẹnu ẹ ni o, ko tubọ maa gbadura fun mi lori ẹ.

Mo ni ko duro ki wọn ra ounjẹ fun un, lo ba n rẹrin-in, lo ni oun, ki oun waa jẹun ni ṣọọbu Iya Biọla, ko jẹ ki oun too de ile gbogbo aye ni yoo ti gbọ pe oun ya ṣọọbu Iya Biọla, oun ko ṣe o. Bi oun ṣe maa n ṣe lati ọjọ aye ẹ niyi, aa ni oun ko fẹ ariwo, emi ti pọpula ju, ki n ma fi okiki temi  ko ba oun. Ni mo ba ni ko maa lọ nigba yẹn o, ṣugbọn ko gbadura fun wa o. Abbey ko jẹ ko lọ bẹẹ ṣaa o, iyẹn n fa a pada, o ni afi ko ba awọn ṣere, nigba to ya, o ni ko ya fọto pẹlu awọn, mo ṣaa n ri i ti wọn n fa ara wọn lọ fa ara wọn bọ, Abbey ko si jẹ ko lọ, afigba to gbowo lọwọ ẹ! N ko mọ iye to fun un, mo ṣaa mọ pe owo to pọ diẹ ni.

Nibi ti wọn ti n fa ọrọ yẹn mọ ara wọn lọwọ ni baba lọọya mi ti pe mi, ni wọn ba ni iroyin ti awọn n gbọ lati ibi ti wọn ti n ṣepade yẹn ko daa. Mo ni ki lo de. Wọn ni awọn kan ti mu ọmọ Ibo kan wa ti wọn ni o loun fẹẹ ra ile ti a n tori ẹ sare kiri, pe oun maa kowo wa lọsẹ to n bọ. Ni baba yẹn ba ni ohun to maa ṣẹlẹ ni pe ki n wa gbogbo owo yẹn lọnakọna, ki a san an laarin ọsẹ yẹn. O ni awọn ti wọn wa nipade ni wọn pe oun, oun si fẹ ki n sọ bi a ṣe maa ṣe e ki oun too pe wọn pada. Ni mo ba ni to ba jẹ ti owo ni, owo wọn ti wa nilẹ niye ti a sọ ọ si yẹn.

Niṣe ni baba yẹn rẹrin-in, to ni mo kare, obinrin bii ọkunrin. Nigba to ya to tun maa pe mi pada, o ni wọn ti gba, gbogbo awọn famili yẹn dẹ ti mura lati wa si ọọfiisi oun, ki wọn waa gbowo naa nijọ keji, o ni ṣẹẹki la maa fun wọn, awọn naa si maa ko iwe ile waa pade wa. Mo ni o ti daa bẹẹ, mo si ki wọn kuu iṣẹ. Aago mẹrin irọlẹ ni wọn pepade, ṣugbọn wọn ni ki awa ti debẹ ni bii aago mẹta. Ọkan mi tun sọ kiji, ile yii ma fẹẹ bọ si mi lọwọ loootọ. Ṣugbọn ẹru n ba mi legbẹẹ kan, ẹru to si n ba mi ni ibi ti mo ti fẹẹ ri irẹsi apo rẹpẹtẹ ti mo n wa yii.

Ibi ti mo ti gbojule tẹlẹ, ko fẹẹ ṣee ṣe mọ. Awọn Alaaji ti mo gbe ọkan si ọdọ wọn, Safu kan daamu lọ ni. Lati aarọ to ti lọ yẹn, ti mo ba sọ fun yin pe ko pada wọle titi aago mẹsan-an lalẹ nkọ! Aya mi tiẹ ja, nigba to to asiko kan, niṣe ni mo n pe e lọ ti mo n pe e bọ. Akọkọ ni pe ko da ibẹ mọ rara. O ni gbogbo ibi ti mo wi yẹn ni wọn ti daru pata, awọn tirela ti ba ibẹ jẹ, awọn ti wọn n ṣe titi ko jẹ ki ibẹ ṣee ri mọ, gbogbo ọọfiisi ati ṣọọbu to wa nibẹ ni wọn ti wo. O ni gbogbo ibi ti mo n sọ yẹn, ko si ile kan nibẹ mọ o. Niṣe ni mo fidi kalẹ wọọ, abiru ki leyi!

Mo ti waa mọ pe to ba di ọjọ keji, foonu mi atijọ yẹn, afi ki n wa a jade. Boya wọn le ba mi rọgbọn da si i ni, nitori bi bẹẹ kọ, Ọlọrun ma jẹ ki aṣiri tu. Loootọ, mo ti sọ fun Akin ko maa ba mi pe awọn oyinbo ẹ ati awọn ti wọn tun jọ n ta irẹsi fun wọn, ṣugbọn nigba to gbọ iye apo ti mo n wa, niṣe lo lanu, o ni nibo ni mo ti fẹẹ ri iyẹn lasiko Koro yii. Amọ o, Ọlọrun Ọba ki i fi ẹni to ba fẹ silẹ o, ki i fi i silẹ rara. Nitori ohun to ṣẹlẹ nijọ yẹn, ara ọtọ ni, ohun ti eeyan ko si ṣe le ṣiyemeji lori ẹ pe Ọlọrun funra ẹ lo ṣe oore naa fun mi niyẹn. Ko ni iyemeji ninu rara.

Ironu ọrọ ti mo ba sun niyẹn, bi mo si ti ki Asubaa tan ni Safu ti de, to ni oun n mura ni toun niyẹn, ṣe ki oun sare ba mi ṣe ogi, abi kin ni mo fẹ. Mo ṣaa ni ko maa lọ si ṣọọbu ni tiẹ, mo n bọ, nitori a maa lọ si ọdọ lọọya lalẹ. Mo ni bawo la waa ṣe fẹẹ ṣe tawọn onirẹsi yii si, o ni Ọlọrun aa yanju ẹ. Ohun ti emi naa ti n ro ni pe bi n ko ba ti ri nọmba ti mo n wa yẹn, mo maa lọ si Tin-can, ni Apapa Wọọfu yẹn funra mi ni, emi ati Safu naa la jọ maa lọ. Bi wọn ba tiẹ ti wo ọọfiisi wọn, awọn kọọkan wa ninu ile nibẹ ti mo le beere wọn lọwọ wọn.

Ṣugbon eto Ọlọrun ọtọ ni, nitori ohun to ba ti ṣe, o ti ṣe e naa niyẹn. Bi Safu ti n sọkalẹ ni foonu mi bẹrẹ si i dun, oun naa lo si pariwo pe ta lo n fi foonu daamu mi laaarọ kutukutu, ki n tete lọọ gbe e o. Nigba ti mo gbe e ni tọhun di Mọla, lo n pariwo ‘holoo holoo!’ Ẹkeji to ti sọrọ ni mo ti mọ pe Alaaji Ṣinkafi ni, ohun ẹ niyẹn, bo ṣe maa n sọrọ gan-an niyẹn! Ẹni ti Safu wa lọ lanaa ti ko mọ ibi to wa lo n pe mi funra ẹ yẹn, ṣe ẹ ri pe iṣẹ Ọlọrun wa yii, awamaridii ni. Ṣugbọn mo beere pe ta ni o, ko le da mi loju. Lo ba ni ṣe emi ko ni foonu kọsitọma mi lọwọ mọ ni!

Mo waa ni ki i ṣe bẹẹ, pe foonu mi bajẹ ni. Lo ba ni Alaaji Ṣinkafi ni. Mo ni emi naa mọ, pe mo kan fẹ ko fi ẹnu ara ẹ sọ ọ ni. Mo kọkọ fẹẹ sọ fun un pe ọmọ mi wa a wa sibẹ lanaa, ṣugbọn mo farabalẹ lati gbọ ohun toun naa n pe mi fun. Lo ba ni emi pa awọn ti, pe oun sọrọ irẹsi fun mi lati ọjọ yii, n ko pe oun pada mọ, pe ọkọ wa to wa loju omi ti de itosi bayii o, wọn ti fẹẹ maa ja irẹsi ibẹ, awọn ko ti i mọ ibi ti awọn fẹẹ ta a si o. Meloo ni mo maa gba nibẹ! Ni mo ba ni ko ma duro mọ o, ko maa bọ ni ọọfiisi ka jọ sọ ọ.

O ni oun ko fẹẹ jade rara o, nitori ọna yẹn ko daa, ṣugbọn nigba to ti jẹ oun loun pe mi yii, oun mọ pe ọrọ to n ja oun laya ti yanju niyẹn, oun bọ bayii bayii. Mo gbọ ti Safu ṣẹṣẹ n dagbere fun Alaaji, niṣe ni mo pariwo mo ni, ‘‘Safu! Ki lo tun n ṣe nibẹ yẹn!” Bẹẹ ni mo ri i to sare jade, ko tiẹ wo ọdọ mi, o mọ pe mo ti n binu niyẹn. Mo ni emi naa kan an lara tan bayii. Mo fẹ ko tete maa lọ si ọọfiisi ko lọọ duro de Alaaji Ṣinkafi, odidi ọkọ oju omi kan ti wa nilẹ bayii, gbogbo irẹsi ti awọn ara Abuja fẹẹ ra yii, ko ti i le debi kankan ninu irẹsi ti wọn n pe mi si. Ẹ e ri i pe iṣẹ Ọlọrun yii ko ṣee tu wo, Ọba alaṣepe ni.

Leave a Reply