Ẹ fadura ran mi lọwọ, ọmọkunrin kan ṣoṣo ti mo bi lo ku sinu ijamba ẹronpileeni yii-Baba Olufade

Alagba George Olufade, baba ọkan ninu awọn awakọ baaluu to gbina lọjọ Ẹti, iyẹn Oloogbe Alfred Olufade, ti sọrọ lẹyin iku ọmọ rẹ. Baba ni ọmọkunrin kan ṣoṣo toun bi naa lo ku lojiji yii, o ni to ba jẹ iku atọdọ Ọlọrun ni, ogo ni f’Ọlọrun, ṣugbọn to ba jẹ eeyan lo wa nidii iku naa, Ọlọrun yoo dajọ fun tọhun.

Bayii ni baba Oloogbe sọ nipa iku ọmọ rẹ ‘O ba ni lọkan jẹ. Adura ni mo nilo. Mo gbadura pe k’Ọlọrun di wa mu, nitori oun nikan lọmọkunrin ti mo ni (iyẹn Oloogbe Alfred).

“O gbọn pupọ, o lawọ, o nitẹriba de gongo, o si mu iṣẹ rẹ lọkun-un-kundun gan-an. Afunni ni, o si fẹran Jesu Kristi.

“Ile ẹkọ awọn pasitọ lo wa ko too lọ sileewe awọn ologun. Oun nikan naa ni ọmọ ogun ofurufu nipinlẹ wa, akanda ọmọ kan ni, koda, oun lo kere ju ninu awọn ẹgbẹ ẹ nigba to kẹkọ gboye. Nigba to si fẹẹ darapọ mọ iṣẹ ologun yii, mo ti i lẹyin lati ibẹrẹ dopin ni, nitori o fẹran ko maa fo lofurufu, mo gba a niyanju, mo si n gbadura fun un.

“Ni gbogbo igba to ba fẹẹ wa baaluu lo maa n sọ fun mi, mo si maa n gbadura fun un. Eyi to lọ gbẹyin yii nikan ni ko sọ fun mi ko too lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ ye Ọlọrun. Adura mi naa kọ lo n gbe e duro latijọ yii, Ọlọrun lo n di i mu.

“Ọlọrun lo fun mi l’Ayọdeji, o si ti gba a, k’Ọlọrun ba mi fun ẹmi rẹ nisinmi.  To ba jẹ latọdọ Ọlọrun ni, ogo ni f’Ọlọrun. To ba jẹ latọwọ eeyan ni, Ọlọrun aa dajọ’’

Bẹẹ ni Baba Ayọdeji, awakọ ofurufu to ṣẹṣe ṣegbeyawo loṣu mẹta sẹyin, sọ nipa ọmọ rẹ to doloogbe ninu ijamba ọkọ ofurufu to gbina lọjọ Ẹti to kọja yii, ni Kaduna.

Baba yii ko ṣai gba awọn ologun nimọran lori iṣẹ wọn, o lo yẹ ki wọn maa mojuto awọn baaluu ti wọn n wa, nitori ọpọlọpọ awọn baaluu yii ni wọn ti gbo, ti wọn ko si mojuto wọn daadaa.

O fi kun un pe wọn tilẹ n daamu awọn awakọ baaluu yii ju, wọn ko fun wọn nisinmi. Alagba Olufade sọ pe ọmọ oun ṣẹṣẹ de lati Maiduguri ni, wọn tun ni ko wakọ lọ si Kaduna. O lo yẹ ki wọn tọju baaluu atawọn to n wa a, ki wọn ma baa ṣe bẹẹ padanu awọn ọlọpọ pipe to n ṣiṣẹ fun wọn tan poo.

Leave a Reply