Ẹ fi awọn OPC Ibarapa tẹ ẹ mu silẹ ko too di pe a bẹrẹ iwọde – Sunday Igboho

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oloye Sunday Igboho ti kilọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati fi awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn ko satimọle nitori ọrọ Wakili ti wọn mu n’Ibarapa silẹ laarin ọsẹ kan ko too di pe awọn ọmọ Yoruba maa jade fun iwọde lori ẹ.

Niluu Oṣogbo lo ti sọrọ naa nibi iwọde Orileede Oodua to waye lọjọ Àbámẹ́ta, Satide, opin ọsẹ yii. O ṣalaye pe ijọloju lo jẹ pe awọn ti wọn mu ẹni to n paayan ni awọn ọlọpaa tun ti mọle.

“Nigba ti Fulani n paayan, ti awọn ọmọ OPC lọọ mu un fọlọpaa, ti ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ati ijọba Naijiria tun fi wọn sakolo, ṣe o yẹ ko ri bẹẹ?

“Ko yẹ bẹẹ, ṣe ẹ wa ri i pe o yẹ ka gbara wa silẹ lọwọ wọn, o ti to gẹẹ. Ṣe ẹ ri ọpọlọpọ awọn agbofinro wa ti ẹ n wo yii, ọmọ Yoruba ni wọn, awọn naa o ni i yinbọn si wa, awọn naa o fẹẹ ku, wọn o si ni i fẹ kawa naa ku”

Ẹ oo ranti pe baba agbalagba naa, Wakili, to jẹ Fulani ni wọn fẹsun kan pe o n huwa laabi oriṣiiriṣii niluu Ibarapa, to si tun jẹ agbọdegba fun awọn ajinigbe-gbowo ko too di pe aṣiri rẹ tu, ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC si fa a le awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lọwọ.

 

Leave a Reply