Ẹ fi ibo gba ara yin silẹ lọwọ idile kan ṣoṣo to n sakoso yin l’Ekoo-Atiku

Monisọla Saka

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti sin awọn olugbe Eko ni gbẹrẹ ipakọ lori ewu to wa ninu ki wọn tun gbe APC depo pada nipele ipinlẹ ati ti aarẹ. Nibi ipolongo ibo aarẹ wọn to waye ni Tafawa Balewa Square, TBS, niluu Eko, ni igbakeji aarẹ tẹlẹ yii ti sọ pe irọ nla to jinna si ootọ lawọn APC n pa pẹlu awọn oriṣiiriṣii nnkan amayedẹrun ti wọn lawọn ṣe sinu ilu, o ni lati bii ọdun mẹtalelogun sẹyin ni wọn ti sọ eto ijọba ipinlẹ Eko di oye idile ti wọn n dari ẹ.

O ni, “To ba jẹ ti afara ori omi, Third Mainland bridge ni, ijọba apapọ lo ṣe e, Opopona Agege Motor Road, atawọn iṣẹ pataki mi-in nipinlẹ yii, iṣẹ ọwọ ijọba apapọ ni. Ijọba APC kan n purọ fun yin pe awọn lawọn ṣe e ni. Akoko ti to fun yin bayii lati gbara yin kuro ninu ide, kẹ ẹ fi ibo le awọn oniyẹyẹ ti wọn ti jokoo ti eto ijọba yii bii oye agboole wọn lati ogun ọdun o le sẹyin kuro, kẹ ẹ si gbe Jandor wọle gẹgẹ bii gomina l’Ekoo”.

Bakan naa ni Atiku tun ṣeleri lati sọ awọn ibudo ti wọn ti n fọ epo rọbi nilẹ yii di ti aladaani lati le ko owo to to biliọnu mẹwaa dọla ($10 billion) jọ fun eto ironilagbara awọn obinrin ati ọdọ lorilẹ-ede yii.

“Awọn eeyan ti n beere ọna ti mo fẹẹ gba ri owo ti mo fẹẹ fi ṣe eto ironilagbara fawọn obinrin atawọn ọdọ, ṣugbọn nigba ti mo ba sọ ibudo ti wọn ti n ṣe epo rọbi ni Warri atawọn ti ibomi-in di aladaani, ma a ri owo yẹn ṣa jọ”.

O waa ṣeleri fawọn eeyan pe oun maa ṣe atunṣe ilu tawọn APC ti bajẹ toun ba depo.

Tẹ o ba gbagbe, ọrọ atunto ilu to ti bajẹ lọwọ awọn ijọba APC yii naa ni oludije dupo gomina lẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Abdulazeez Ọlajide Adediran tawọn eeyan mọ si Jandor, maa n tẹnu mọ nigbakugba to ba n polongo ibo.

Nigba toun naa n sọrọ nibi ipolongo ibo yii gẹgẹ bo ṣe ti maa n sọ tẹlẹ, o ni,  “Lati bii ọdun mẹtalelogun sẹyin, a o ti i ri nnkan gidi kan tọka si l’Ekoo, akoko si ti to bayii lati sọ Eko di ilu pataki tẹ ẹ ba le gbe mi depo pẹlu ibo yin.

Iṣẹ ati oṣi ti waa gbilẹ gidi gan-an lati igba ti Sanwo-Olu ti gbajọba, pẹlu bo ṣe n fọnnu kiri pe biliọnu mẹwaa Naira loun run le ọrọ igbanisiṣẹ nipinlẹ Eko.

Emi ati Funkẹ Akindele ti yoo ṣe igbakeji mi ti n ṣapa wa, a n gbaayan si iṣẹ, bẹẹ la n sanwo ori wa, ṣugbọn Sanwo-Olu ati igbakeji wọn ko mọ nnkan ti sisan owo-ori n jẹ.

“Ẹ jẹ ki n waa lo anfaani yii lati sọ fawọn olugbe Eko pe awọn ọmọọta ati agbero tẹ ẹ ni wọn n yọ yin lẹnu, tijọba si kọ lati fopin si i, emi gẹgẹ bii ẹni kan yoo fi igbagbe si gbogbo wahala awọn agbero onimọto, atawọn ti wọn n yọ awọn oniṣowo lẹnu ninu ọja ti n ba di gomina. Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe ileri wa fun yin niyi, a o si ni i ja yin kulẹ.

Lasiko to n sọrọ nibi ipolongo ibo naa, igbakeji oludije dupo aarẹ lẹgbẹ PDP, to tun jẹ gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, sọ fawọn ero to wa nibẹ pe oun ti mọ ni toun pe awọn olugbe Eko ti ṣetan lati rọ ibo lọpọ yanturu fawọn lọdun 2023.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga apapọ ẹgbẹ PDP, Iyorchia Ayu, sọ pe Atiku yoo sọ ilẹ Naijiria di ilu to dara ju lọ nilẹ Afrika. Bakan naa lo tun fi wọn lọkan balẹ pe ti wọn ba le fibo wọn ṣatilẹyin fun un to fi depo aarẹ, Atiku yoo fagi le ọrọ owo-ori tawọn eeyan n san ni ilọpo ilọpo.

 

Leave a Reply