Ẹ fun emi naa ni mọto o: Pariolodo bẹẹ awọn figbe bọnu

Adewale Adeoye

‘Bo tilẹ jẹ pe ile akọku ti n ko ti i pari tan debi ti ọkan mi n fẹ ni mo n gbe bayii, inu mi n dun pe inu ile ara mi ni mo n gbe. Ohun kan ṣoṣo ti ma a bẹ gbogbo ẹyin ololufẹ mi fun ni pe kẹ ẹ jọ ọ, kẹ ẹ dawo jọ fun mi, ki n le fi ra mọto lati ma a maa gun kaakiri ilu. Ọjọ ọhun ti pẹ diẹ bayii ti emi paapaa ti wa nidii iṣẹ tiata, mi o ti i da ra mọto ri nigbesi aye mi, ẹsẹ ni mo fi n gba ilu kaakiri, ko ṣẹṣẹ digba ti mo ba ku tan kẹ ẹ too maa ṣedaro mi tabi kẹ ẹ waa sọ pe ẹ fẹẹ maa ṣohun gidi kan lati maa fi ṣeranti mi lọdọọdun, igba ara la n bura ni kẹ ẹ ba mi fọrọ mọto to n jẹ mi niya yii ṣe.’ Eyi lọrọ to n jade lẹnu agba oṣere tiata nni, Ṣọla Ọlaonipẹkun, ẹni tawọn eeyan mọ si, Pariolodo ninu awọn fiimu agbelewo gbogbo to n jade lorileede wa.

Odu ni Pariolodo, ki i ṣe aimọ-foloko, paapaa ju lọ, awọn to mọ ipa pataki to ko ninu fimu agbelewo kan bayii ti Ọgbẹni Thompson ati Dehinde gbe jade lọpọ ọdun sẹyin. Latigba naa si ni Pariolodo ti n kopa daadaa ninu awọn fiimu agbelewo gbogbo.

Ninu fidio oniṣeju diẹ kan bayii ti oṣere naa ṣe sita lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, osu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lo ti n rawọ ẹbẹ sawọn araalu, paapaa ju lọ awọn ololufẹ rẹ gbogbo ti wọn wa nilẹ yii ati l’oke-okun pe ki  wọn ṣeranlọwọ mọto foun naa gẹgẹ bi wọn ti ṣe fun awọn bii Iya Gbonkan ati Lalude, ti wọn fun ni mọto laipe yii.

Pariolodo ni, ‘Mi o tọrọ ohun to pọ ju lọwọ yin rara, mo si mọ pe ẹ le ṣe e fun mi ni mo ṣe n beere rẹ lọwọ yin bayii, bi mo ti ṣe n gan mọto kaakiri igba gbogbo ti mo ba n lọ si lokeṣan yii ki i ṣe ohun to daa rara. Ọpọ ode ere lo yẹ ki n maa lọ, ṣugbọn ti mi o ki n le lọ nigba ti mi o ni ohun irinsẹ.

Ọjọ kan tiẹ wa, to jẹ pe emi ni mo lọọ ṣe abolode fẹ ẹ loju ti wọn n pe ni MC lode pataki kan, agba olorin nni, Pasuma lo waa ṣere lojọ naa, gbara to pari ere tan lo ti ko sinu mọto rẹ, to si sa lọ, nibi ti emi duro si ti mo ti n wa mọto ti ma a wọ pada lọ sile lawọn tọọgi kan ti ya bo mi, wọn gbọn mi wo yẹbẹ-yẹbẹ, nigba ti wọn ri i pe ko sowo kankan lapo mi ti ma a fun wọn ni wọn bẹrẹ si i sọko ọrọ si mi. Oju gba mi ti lọjọ naa lọhun-un. Inu mi ko si dun rara si bi wọn ṣe yẹyẹ mi nita gbangba.

Fun idi eyi, Pariolodo ni kawọn ojulowo ololufẹ rẹ dide iranlọwọ foun naa lati ra motọ toun yoo maa gun bayii.

O ni bi wọn ba le ṣe eyi foun, inu oun yoo dun gidi ni. Bakan naa lo gbadura gidi fawọn ololufẹ rẹ gbogbo pe nibi ti wọn yoo ti mu owo ọhun jade lati fi ra mọto naa, Oluwa maa fi ọpọ rọpo fun wọn laipẹ ọjọ.

Leave a Reply