Ẹ fun wa laaye lati lo awọn nnkan abalaye lori wahala eto aabo – Awọn ọdẹ

Florence Babaṣọla

Agbarijọpọ awọn ọdẹ [local hunters] nipinlẹ Ọṣun, ti rawọ ẹbẹ si Gomina Adegboyega Oyetọla lati fun wọn lanfaani lati lo awọn nnkan abalaye ilẹ wa lori idojukọ wahala eto aabo to n waye lojoojumọ kaakiri bayii.

Olori awọn ọdẹ ọhun nilẹ Ijeṣa, Oloye Ogunbiyi Akamọ, ṣalaye pe nibi ti nnkan de duro bayii, o yẹ ka pada si ẹsẹ aarọ, iyẹn lilo awọn agbara ti Eledua fi jinki iran Yoruba.

Nibi ipade apero kan ti ọfiisi oludamọran pataki fun gomina lori itaniji awọn araalu ṣe ninu ọgba ileewe Ileṣa Grammar School, niluu Ileṣa, lawọn ọdẹ naa ti sọ pe oogun abẹnugọngọ n bẹ lọwọ awọn Ogoje Ilu, to si gbona janjan, to n ṣiṣẹ ni wara-n-sesa.

Ogunbiyi sọ siwaju pe loootọ nipinlẹ Ọṣun wa lara awọn ipinlẹ to ṣi ni alaafia diẹ lorileede yii, sibẹ, o yẹ kijọba ri i pe ibaṣepọ to dan mọnran wa laarin awọn ikọ alaabo tijọba ati tagbegbe kọọkan nitori awọn ni wọn mọ apade ati alude agbegbe kọọkan.

O ni ijọba ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn ikọ alaabo to wa kaakiri, ti wọn ni awọn nnkan abalaye a-jẹ-bii-idan lọwọ nitori wọn ni imọ ijinlẹ iwadii nilana ti Yoruba lati fi koju wahala eto aabo.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọbanla ti ilẹ Ijeṣa, Dokita Matthew Ogedengbe, sọ pe iṣẹ takuntakun ni Gomina Oyetọla ti ṣe lori eto aabo nipinlẹ Ọṣun, o si tun rọ ọ lati ma ṣe dawọ duro nipa sisọ Ọṣun di apewaawo fawọn ipinlẹ to ku.

Bakan naa ni Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ṣapejuwe Oyetọla gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe to n lo ọgbọn idari rẹ lati fi ṣakoso ipinlẹ yii lọna to yatọ, o si dupẹ lọwọ awọn araalu fun aduroti wọn fun iṣejọba naa.

Oludamọran pataki fun gomina lori itaniji awọn araalu, Ọnarebu Ọlatunbọsun Oyintiloye, sọ pe eredi eto naa ni lati le jẹ ki awọn araalu naa lẹnu ninu iṣejọba Gomina Oyetọla, ki ohunkohun ti wọn ba n fẹ lọdọ ijọba si le di ṣiṣe kiakia.

Leave a Reply