Ẹ fura o! Awọn Fulani Bororo bii ọọdunrun ti ya wọ ilu Ibadan

Dada Ajikanje

Niṣe ni jinnijinni da bo awọn eeyan agbegbe Majẹ, Soka, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe deede ri awọn Fulani darandaran bii ọọdunrun (300) to ya wọ adugbo naa. Mọto nla mẹta ni wọn kun inu rẹ fọfọ.

Oludari egbẹ Oodua People’s Congress, (OPC), Rotimi Olumọ, lo ṣalaye ọrọ yii fawọn oniroyin niluu Ibadan. Ọkunrin naa ni ẹnikan lo ta oun lolobo iṣẹlẹ naa, oju ẹsẹ loun si lọ sibẹ. Lasiko naa lo ni oun ri bọọsi nla nla mẹta ọhun to ko awọn eeyan naa wa sibẹ.

Olumọ ni, ‘‘Oriṣiiriṣii awọn eeyan ni wọn n pe mi laaarọ yii, ti wọn si n fi to mi leti pe awọn ri awọn Fulani darandaran kan ni agbegbe Sanyo ti wọn pọ rẹpẹtẹ ni nnkan bii aago meje aarọ.’’

Ọkunrin yii ni awọn Fulani darandaran lawọn eeyan naa, irin ati iṣesi wọn si mu ifura dani, eyi loun ko fi gba wọn laaye lati bọ silẹ ninu awọn ọkọ ti wọn gbe wa naa.

O ni ohun to mu ki ọrọ yii jẹ ijọloju ni pe adugbo naa ki i ṣe Sabo ti awọn Hausa ati Fulani maa n wa ati pe ko si ẹya mi-in ninu awọn eeyan yii ju Fulani Bororo lọ. Nigba tawọn si beere ibi ti wọn n lọ ati ibi ti wọn ti n bọ, wọn ko ṣalaye kankan fawọn.

Ọga awọn OPC yii ni oju ẹsẹ lawọn fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa Sanyo leti, ti wọn si wa sibẹ. Awọn ọlọpaa yii lo ko awọn mọto mẹtẹẹta naa pẹlu awọn Fulani yii lọ si agọ wọn.

Ọkunrin yii ni ọkan ninu awọn Bororo yii sọkalẹ ninu mọto, to si n ba ọlopaa naa sọrọ, ṣugbọn oun ko mọ ohun ti wọn n sọ.

O ni pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhẹ, gbogbo eeyan ilu lo gbọdọ joye oju lalakan fi n ṣọri.

Alukoro ọlọpaa ko ti i sọ nnkan kan lori ọrọ naa di ba a ṣe n sọ yii.

One thought on “Ẹ fura o! Awọn Fulani Bororo bii ọọdunrun ti ya wọ ilu Ibadan

Leave a Reply