Ẹ fura o, NAFDAC ti mu awọn to n ṣe ayederu oogun oyinbo l’Ekoo 

Adewale adeoye

Ajọ to n ri sọrọ ounjẹ jijẹ ati ohun mimu pẹlu oogun lorileede yii, ‘National Agency for Food And Drug Administration Control’ (NAFDAC), ẹka tipinlẹ Eko ti fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran kan to jẹ pe wọn ti jingiri ninu ṣiṣe ayederu oogun oyinbo. O kere tan, bii ọọdunrun miliọnu Naira (#300,000.000) ni owo ayederu oogun oyinbo ti wọn gba lọwọ wọn.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Tyre Village, ninu ọgba ileetaja igbalode Trade Fair Complex, to wa nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran naa n lo fun iṣẹ to lofi sofin ti wọn n ṣe ọhun.

Lara awọn ayederu oogun oyinbo ti wọn ba lakata wọn ti wọn n ṣe lọwọ ni Amoxicillin 500mg, Ampiclox atawọn eroja kan ti wọn fi n ṣe awọn ayederu oogun oyinbo naa.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘’Apapọ owo ayederu oogun oyinbo ta a gba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa jẹ miliọnu lọna ọọdunrun Naira, awọn ayederu oogun ti wọn n ṣe maa ni ipalara nla fawọn araalu ti ko mọ pe wọn o ki i ṣe ojulowo bi wọn ba lo o tan. A ti ko gbogbo awọn ayederu oogun oyinbo naa kuro nibi ta a ti ba wọn. Bẹẹ la ti fiwe pe awọn to ni ileeṣẹ naa pe ki wọn waa sọ tẹnu wọn lọdọ wa.

A n ṣewadi nipa iṣelẹ ọhun lọwọ, ta a si maa foju awọn afurasi ọdaran ta a ba gba mu bale-ẹjọ.

NAFDAC waa rọ awọn araalu pe ki wọn ṣakiyesi daadaa ko too di pe wọn oogun tabi ohun jijẹ tabi mimu mi-in lasiko yii, nitori pe ọpọ ninu awọn afurasi ọdaran wa nita bayii ti wọn n ṣe ayederu nnkan lati jere ajẹju.

Leave a Reply