Ẹ fura o, o le ni igba eeyan to lugbadi Korona l’Ọṣun laaarin ọjọ meji pere

Florence Babaṣọla

 

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti n kọminu bayii lori ọna ti arun Koronafairọọsi n gba tan bii ina ẹẹrun nipinlẹ naa.

Nigba ti ajọ NCDC gbe akọsilẹ iye awọn to lugbadi arun naa lọjọ Tọsidee, ọsẹ yii jade, eeyan ọgọfa lo jẹ ara ipinlẹ Ọṣun nibẹ, awọn mejidinlọgọrun-un ni wọn si tun gbe jade bayii pe wọn lugbadi rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

Idi niyẹn ti Kọmiṣanna feto ilera, Dokita Rauf Isamọtu, fi n pariwo pe awọn eeyan ko fi ọwọ to dara mu ilera ara wọn rara, o si da bii ẹni pe wọn ko mọ agbara ti arun naa ni lọwọlọwọ.

Isamọtu ṣalaye pe awọn ilana to rọrun, ti ko si jọ awọn eeyan loju ni ajọ NCDC gbe kalẹ lati fi koju arun yii, ṣugbọn ọwọ yẹpẹrẹ lawọn kan fi mu un, eleyii to si n da wahala silẹ bayii.

O ni pẹlu bijọba ṣe n pariwo to, sibẹ, awọn kan ko dẹkun pipatẹ inawo lai bọwọ fun ofin jijinna sira ẹni, ọpọ ni ko lo ibomu laarin ilu, bẹẹ ni ọwọ fifọ loorekoore ko si ninu erongba ọkan ẹlomi-in.

Isamọtu waa ran awọn eeyan leti pe ẹmi gigun lo n sanya, bi ko ba si si alaafia, ko si nnkan to rọrun fun ẹnikẹni lati ṣe.

 

Leave a Reply